Buhari n ṣiṣẹ fawọn Fulani lati so Naijiria di tiwọn ni o – Gomina Benue 

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Benue, Ọgbẹni Samuel Ortom, ti fẹsun kan Aarẹ Muhammadu Buhari pe ta a ba foju-inu wo ohun to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria yii nipa iṣoro aabo to dẹnu kọlẹ patapata, ta a ba si foju-inu wo ihuwasi Aarẹ Buhari, ohun to foju han ni pe niṣe ni Buhari n ṣiṣẹ fawọn Fulani lati sọ Naijiria di tiwọn.

Orthom sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, nigba to n fi ero rẹ han lori bawọn Fulani darandaran atawọn janduku agbebọn ṣe n da ẹmi awọn araalu legbodo lemọlemọ nipinlẹ naa, ati lawọn ipinlẹ Aarin-Gbungbun Ariwa.

Bakan naa ni gomina ọhun fi ẹdun ọkan rẹ han, o ni eeyan to ju aadọrin lọ lawọn agbebọn ti ran lọ sọrun apapandodo laarin ọsẹ meji pere lawọn ijọba ibilẹ mẹta nipinlẹ naa.

Samuel Orthom ni “Mo ti wo ohun to n ṣẹlẹ bayii daadaa, o si ye mi. Niṣe ni Mista Purẹsidẹnti n ṣiṣẹ kawọn Fulani yii le sọ Naijiria di tiwọn. Ihuwasi ẹ lo fi han bẹẹ.

“Awọn igbesẹ to gbe atawọn to kuna lati gbe fihan pe Aarẹ yii ki i ṣe Aarẹ Naijiria, Aarẹ awọn Fulani nikan ni, ọrọ yii ṣẹṣẹ ye mi ni.

“Orileede yii ti di ilu ta o mọ olori, ta o mọ ọmọ-ẹyin, ti Aarẹ ba paṣẹ pe kawọn agbofinro yinbọn pa ẹnikẹni ti wọn ba ri ibọn AK-47 lọwọ ẹ lai bofin mu, ṣugbọn ti minisita feto aabo fesi pe awọn o le maa yinbọn paayan lẹsẹkẹsẹ bẹẹ yẹn, ẹ gbọ, ta ni ka waa gba pe o n ṣakoso awọn ologun?

“Aarẹ gbọdọ wa nnkan ṣe, to ba jẹ oun ni Aarẹ orileede Naijiria loootọ, eyi ti ẹya to ju okoolerugba lọ wa ninu rẹ, ko mọ pe gbogbo wa la dibo foun, o si ti bura, o ti jẹjẹẹ nigba to fẹẹ gbọpa aṣẹ pe oun maa pese aabo fun awọn araalu ati dukia wọn.

“Ohun to n ṣẹlẹ lọwọ yii o boju mu, ko gbọdọ maa lọ bẹẹ, tori awọn eeyan ipinlẹ Benue ti sun kan ogiri, wọn ti ni suuru to, wọn o le kawọ gbera mọ pẹlu bawọn Fulani agbebọn ṣe sọ ẹmi wọn di meji eepinni niluu baba wọn.”

 

Leave a Reply