Buhari rin irinajo lọ si Dubai, wọn lo lọ fun ipade ọrọ-aje

Faith Adebọla

Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti kuro niluu Abuja bayii, o ti lọ sorileede UAE, iyẹn United Arab Emirates, ti olu-ilu rẹ jẹ Dubai, lati kopa ninu ipade pataki kan.

Ipade ọhun, gẹgẹ bi atẹjade ti Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, fi lede lọjọ Wẹsidee, ọsẹ yii, o ni Buhari wa lara awọn to maa sọrọ nibi apero ti ọgọọrọ awọn alaṣẹ ilu, olori orileede ati awọn olokoowo agbaye to to aadọwaa (190) maa pesẹ si.

Akori ipade, ‘EXPO 2020’ ọhun ni: “Rironu papọ lati mu ọjọ ola rere wa.” O lawọn ọrọ ati ajọsọ to maa waye nipade naa maa da lori bi ifọwọsowọpọ ati ajọṣe tuntun ṣe maa waye laarin awọn ọgba ọjẹ lẹka iṣowo agbaye, ti eyi yoo si mu ki ọjọ-ọla dara, paapaa fun ilẹ adulawọ.

Yatọ si ti apero naa, Aarẹ Buhari maa ba awọn ti wọn nifẹẹ lati waa da okoowo silẹ ni Naijiria sọrọ, o maa ṣabẹwo si ibi ipatẹ nnkan aritọkasi Naijiria to wa ni Dubai, bẹẹ lo maa ṣepade pẹlu awọn alaṣẹ ilu Dubai, titi kan Ọlọla ju lọ, Sheikh Mohamed bin Zayed Al Nahyan, Ọmọọba Alade ilu Dubai, Igbakeji Aarẹ ati olori ijọba UAE, Sheikh Mohammed bin Rashid Al Maktoum.

Adeṣina ni ti Buhari ba pari awọn eto wọnyi tan ni yoo too pada sile.

Leave a Reply