Chidinma to gun ọga ileeṣẹ tẹlifiṣan lọbẹ pa l’Ekoo ni kawọn mọlẹbi ọkunrin naa foriji oun, oun o fẹẹ ku

Faith Adebọla, Eko

Bo ti wu ki ọti pa eeyan to, bo si ti wu keeyan fibinu huwa to, bo pẹ, bo ya, ọti ati ibinu naa aa da loju onitọhun, kedere ni abajade ohun to ṣe nigba ti ọti n pa a, tinu si n bi i yoo han si i, ṣugbọn abamọ ki i ṣaaju ọrọ, ẹyin ọrọ lo maa n wa, igbẹyin si lo maa n dun olokuu ada, bẹẹ lọrọ ri fun ọmọbinrin akẹkọọ Fasiti Eko (UNILAG), ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Chidinma Adaora Ojukwu, ti wọn fẹsun kan, to si ti jẹwọ pe loootọ loun gun ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Super TV, Ọgbẹni Osifo Ataga, lọbẹ pa, ọmọbinrin naa ti n rawọ ẹbẹ bayii pe kawọn mọlẹbi oloogbe fori ji oun, ki wọn ma jẹ kọrọ oun ja siku.

Lopin ọsẹ to kọja lọ yii, nigba tafurasi ọdaran naa n ba awọn oniroyin kan sọrọ, wọn lo sọ pe o dun oun toun ṣeku pa Ọgbẹni Ataga, o loun o paayan ri, ki wọn ṣaanu oun, oun o fẹẹ ku.

“Mo kabaamọ pe mo ṣeku pa Mista Ataga. Mi o mọ nnkan to le ṣẹlẹ si mi o, ṣugbọn mi o fẹẹ ku. Ẹ jọọ, ẹ ma jẹ ki n ku lori ọrọ yii, mi o paayan ri laye mi,” bẹẹ ni wọn lọmọbinrin yii sọ pẹlu omije loju.

Ọsan Ọjọbọ, Tosidee, to kọja yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣafihan afurasi ọdaran yii ni olu ileeṣẹ wọn to wa n’Ikẹja, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, funra ẹ lo ṣalaye diẹ nipa ohun to ṣẹlẹ.

Odumosu ni inu otẹẹli kan tawọn forukọ bo laṣiiri lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, lọmọbinrin to wa nipele kẹta ẹkọ imọ ibanisọrọ kari-aye (Mass Communication) ni University of Lagos ti huwa ọdaran rẹ, niṣe lo gun ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan ẹrọ ayelujara Super TV, Ọgbẹni Micheal Usifo Ataga, lọbẹ pa sinu yara toun atiẹ ti jọọ ṣere ifẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, loṣika tan tẹsẹ mọrin ẹda yii ba fere ge e, o sa lọ sọdọ awọn obi rẹ ni Yaba, ibẹ naa si lawọn ọlọpaa tọpinpin ẹ de ti wọn fi ri i mu.

Chidinma naa fẹnu ara ẹ sọrọ, o ni loootọ loun gun oloogbe naa lọbẹ pa, ṣugbọn ki i ṣe pe oun fẹẹ ṣeka fun un o, oun fi ọbẹ naa gbeja ara oun ni, (self-defence), loun ṣe bii aṣa awọn eleebo.

Leave a Reply