Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin kan, Oluwafẹmi Damilọla, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisireeti agba to wa lagbegbe Ọka, niluu Ondo, lori ẹsun lilu awọn asẹwo mẹrin, Glory David, Akere Bright, Valria Isaac and Ngozi Okoro, ni jibiti lẹyin to ba wọn lo pọ tan.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye lagbegbe Sabo, Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.
Ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn ọhun ni wọn fẹsun kan pe o kọ lati san ẹgbẹrun marundinlaaadọta Naira to jẹ owo iṣẹ awọn oniṣowo nabi yii fun wọn lẹyin to ba wọn sun tan.
Dipo ti iba si san owo ọhun fun wọn gẹgẹ bii ileri to ṣe, ṣe lo tun tan wọn pẹlu bo ṣe fi ayederu alaati pe oun ti sanwo naa ṣọwọ si wọn.
Ẹsun meji ti Agbefọba, Akao Mọremi, fi kan olujẹjọ ọhun ni hihuwa to le da omi alaafia ilu ru ati lilu awọn aṣẹwo mẹrin ni jibiti nipa biba wọn sun lọna aitọ, to si tun kọ lati sanwo iṣẹ wọn fun wọn.
Awọn ẹsun wọnyi lo ni o ta ko abala ojilenigba le mẹsan-an (249) ati ọtalelọọọdunrun (360) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.
Agbefọba ni awọn marun-un loun ti ṣeto silẹ ti yoo jẹrii ta ko olujẹjọ nigba ti igbẹjọ ba n tẹsiwaju. O bẹbẹ fun sisun ẹjọ naa siwaju ki oun le lanfaani lati ṣe agbeyẹwo iwe ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa daadaa.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Ọgbẹni S. A. Iluyẹmi, ni oun fẹ ki ile-ẹjọ naa fi aaye beeli rẹ silẹ, ki wọn si yọnda rẹ fun oun. O fi da kootu ọhun loju pe onibaara oun yoo ti sanwo awọn asẹwo naa fun wọn ki wọn too tun pada jokoo lori ọrọ naa.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Charity Adeyanju gba ẹbẹ agbẹjọro naa wọle, o ni oun fa olujẹjọ le amofin naa lọwọ, ko si ri i daju pe o sanwo ti wọn tori ẹ pe e lẹjọ ko too di ipari oṣu Kẹfa yii.