Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọga agba Fasiti Ọṣun, Ọjọgbọn Clement Ọdunayọ Adebooye, ti sọ pe o pọn dandan fun akẹkọọ to ba wa sileewe naa lati ni imọ nipa iṣẹ ọwọ kan.
Lasiko ayẹyẹ igbaniwọle ti wọn ṣe fun awọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ wọ fasiti naa lọjọ Wẹsidee, ni Ọjọgbọn Adebooye ṣalaye pe lọgan ti akẹkọọ ba ti wọle ni yoo ti mu iṣẹ-ọwọ kan ti yoo ṣe.
O ni bi akẹkọọ ṣe n kawe naa ni yoo maa kọ iṣẹ-ọwọ nitori awọn ko fẹ ki awọn akẹkọọ awọn jade lai ri iṣẹ ṣe, bi wọn ba si ti pari ni wọn yoo gba satifikeeti meji; ọkan fun ti fasiti, ekeji fun ti iṣẹ-ọwọ ti wọn kọ.
Lara ọna lati jẹ ki awọn akẹkọọ yii le da duro lẹyin ti wọn ba kuro nileewe, Ọjọgbọn Adebooye sọ pe ẹyawo ẹlẹgbẹrun lọna igba Naira ti wa nilẹ fun ọkọọkan eyi to ba ti le sọ pato nnkan to fẹẹ fi owo naa ṣe, ọdun marun-un ni wọn yoo si fi da owo naa, to ni ele ida kan ninu ida ọgọrun-un, pada.
Ọga agba yii sọ siwaju pe ki awọn akẹkọọ ti wọn ṣẹṣẹ wọle naa ki ara wọn ku oriire nitori ninu awọn ẹgbẹrun mẹfa ti wọn mu UNIOSUN bii fasiti akọọkọ, ẹgbẹrun mẹrin pere ni awọn mu.
O waa kilọ fun awọn akẹkọọ naa lati mọ pe bi wọn ṣe ni ominira lati lo gbogbo oju ikanni ayelujara naa ni wọn gbọdọ ṣọra nipa wọn.
O ni ki i ṣe gbogbo nnkan tabi iroyin ti wọn ba ri lori ikanni ayelujara ni wọn gbọdọ maa gbe kaakiri, wọn ko si gbọdọ sọ ọrọ alufansa to le ba orukọ fasiti naa jẹ.
Ọjọgbọn Adebooye rọ awọn akẹkọọ naa lati sa fun kiko ẹgbẹ buburu, ki wọn yago fun ilokulo oogun oloro, ẹgbẹ okunkun, magomago ninu idanwo, iwa jagidijagan ati ifipabanilopọ.
O ni ẹnikẹni ti ajere iru iwa bẹẹ ba ṣi mọ lori yoo foju winna ofin, o si le yọri si lile iru akẹkọọ bẹẹ kuro nileewe patapata.