Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ẹbi, awujọ bọọlu ati gbogbo ẹni to mọ Oloogbe Kaṣimawo Laloko to figba kan jẹ akọni-mọ-ọn-gba agbabọọlu NFF nilẹ yii, to si tun jẹ olori Parakoyi ilẹ Ẹgba lapapọ.
Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta yii, ni Oloye Kaṣimawo Laloko dagbere faye nileewosan Sacred Hearts to wa l’Abẹokuta, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin( 76) ni.
Ninu atẹjade to ti ọfiisi Akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, jade lọjọ Aje ọsẹ yii ni Dapọ Abiọdun ti ṣalaye pe adanu nla ni iku Laloko lẹka awọn agbabọọlu nipinlẹ Ogun, nilẹ Naijiria ati ni gbogbo agbaye pata.
Gomina tẹsiwaju pe yatọ si ẹka agbabọọlu ti oloogbe yii ti ṣiṣẹ takuntakun, o ni Kaṣimawo ko fi ọrọ okoowo naa ṣere. Eyi naa lo fa a ti wọn fi fi i jẹ oye olori Parakoyi gbogbo ilẹ Ẹgba pata.
Oloogbe Kaṣimawo Laloko da ileewe nipa ere bọọlu silẹ l’Orile-Imọ, eyi ti Pepsi Football Academy ti ara ẹ dide, to si jẹ pe ọpọ awọn agbabọọlu ọjẹ wẹwẹ lo ti ibẹ dide ti wọn di ẹni nla.
Ọkan ninu awọn eeyan to nigbagbọ ninu gbigba akọni-mọ-ọn-gba ilẹ wa lati kọ awọn eeyan ni bọọlu ni baba to doloogbe yii, oun ko fara mọ ka maa kowo foyinbo ti yoo waa kọ awọn eeyan ilẹ yii ni bọọlu gbigba, nitori ẹnikan to nigbagbọ ninu gbigbe nnkan Naijiria larugẹ ni.