Ọkọ akẹru sa f’ewurẹ, lo ba tẹ ọmọleewe mẹrin ati ọlọkada kan pa n’Ibadan                                                 

Faith Adebọla

Iran buruku niran ọhun, ibanujẹ nla gbaa ni iṣẹlẹ ijamba ọkọ akẹru kan ti wọn lo ya lọọ pa awọn ọmọọlewe mẹrin nifọnna ifọnṣu lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde yii, n’Ibadan, o tun pa ọlọkada kan to gbe awọn awọn ọmọ ọhun pẹlu.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ileewe Ejioku Secondary School, loju ọna to lọ si Iwo, nijọba ibilẹ Lagelu, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lawọn majeṣin naa ti n kawe, ibẹ ni wọn ti jade, ti wọn lọ sile awọn obi wọn, ki ijamba yii too sọ wọn doloogbe.

Wọn ni awọn ewurẹ ati aguntan rẹpẹtẹ kan ni wọn ya sori titi, ti wọn si di ẹgbẹ kan ọna naa, ojiji ni wọn ni ọkọ akẹru naa kan wọn, lọrọ ba di rabaraba, bo si ṣe pẹwọ fawọn ewurẹ ọhun lo mu ko ya si ọna ọlọna, niṣe lo ṣe kongẹ ọlọkada to ko awọn awọn ọmọleewe mẹrin sẹyin, ni wọn ba ṣubu yakata, wọn ni nibi ti wọn ṣubu si ọhun ni ọkọ yii tẹ gbogbo wọn pa mọ.

Iṣẹlẹ naa gbona lara awọn ọmọọlewe yooku, atawọn ọdọ ti wọn wa lagbegbe ọhun, ẹsẹkẹsẹ ni wọn lawọn eeyan naa ti dana sun ọkọ akẹru to ṣokunfa ijamba yii, bo tilẹ jẹ pe dẹrẹba ọkọ ọhun ribi tu pọrọ, to si sa mọ wọn lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ori ọkada lawọn ọmọleewe naa wa, eyi lo si ṣee ṣe ko fa a ti ọlọkada naa ko fi le tete ribi ya si.

O lawọn agbofinro ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, latari bawọn ọmọleewe atawọn janduku ṣe fẹẹ da wahala silẹ fawọn ọlọkọ loju ọna naa. Fadeyi ni awọn ti gbe oku awọn maraarun lọ sọsibitu, awọn si ti bẹrẹ iwadii lati mọ dẹrẹba ati ẹni to ni mọto naa.

Leave a Reply