Faith Adebọla
Gbajugbaju oniroyin ati ondije dupo aarẹ ilẹ wa nigba kan, Oloye Dele Mọmọdu, ti tun gbe agbada oṣelu wọ lẹẹkan si i, lọtẹ yii, ẹgbẹ oṣelu alatako to pọ ju lọ nilẹ wa, Peoples Democratic Party, lo n ba lọ.
Ninu atẹjade kan tọkunrin ọhun fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lo ti sọ ipinnu rẹ di mimọ, o ni lẹyin toun yiiri ipo ti ọrọ oṣelu ati orileede wa wa, oun ri i pe ọna pataki kan toun fi le kun wọn lọwọ lati wa iyanju siṣoro wa.
Mọmọdu ni: “Mo ti ba awọn eeyan sọrọ kaakiri loriṣiiriṣii, o si ṣe kedere si mi pe pẹlu ipo ẹlẹgẹ ati ewu ti orileede wa ba ara ẹ yii, paapaa bi nnkan ṣe fọju pọ lati bii ọdun mẹfa sasiko yii, ẹgbẹ kan ṣoṣo to le tun nnkan ṣe ta a ba kun wọn lọwọ ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Eyi ṣe wẹku pẹlu bi mo ṣe maa n sọrọ ta ko awọn eto raurau ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) n gbe kalẹ, ati bawọn adari wọn ṣe n ṣakoso, eyi to ti mu ki ọpọ nnkan to ṣeyebiye bọ sọnu mọ orileede wa lọwọ, iṣọkan ti sọnu, aabo sọnu, ẹkọ iwe to jiire sọnu, ajọṣepọ sọnu, ọrọ-aje sọnu, aasiki sọnu, nnkan amayederun dawati, ju gbogbo ẹ lọ, ilana iwa rere ati tọmọluabi ko si mọ, gbogbo nnkan kan ri jugbujugbu ni.
Fun idi yii, inu mi dun lati kede pe mo ti di ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP bayii, tori tọrun ni mo fi bọ sinu ẹgbẹ naa, ẹgbẹ nla to maa gbegba oroke ni.
O dun-unyan pe awọn aṣeyọri ti ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe latẹyinwa, lọdun mẹrindinlogun ti wọn fi ṣakoso, kaka kawọn aṣeyọri naa pọ si i, niṣe lẹgbẹ oṣelu APC waa ba gbogbo ẹ jẹ pata, wọn si ti fawọ aago itẹsiwaju naa sẹyin kọja aala.”