Ile-ẹjọ ni Oluwoo ko gbọdọ fi ẹnikẹni joye Mufti Agba fun ilẹ Yoruba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo ti paṣẹ pe Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ko gbọdọ fi ẹnikẹni jẹ oye Mufti Agba (Grand Mufty) ti ilẹ Yoruba.

Aarẹ agbarijọpọ awọn Imaamu ati Aafa nilẹ Yoruba, Sheik Jamiu Kewulere atawọn marun-un mi-in ni wọn wọ Oluwoo lọ si kootu nipasẹ agbẹjọro wọn, Kazeem Ọdẹdeji, lati ka a lọwọ ko nipa ọrọ oye naa.

Ọba Akanbi ti kọkọ kede pe ọjọ Abamẹta, Satide,  ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ni oun yoo fi oludasilẹ ijọ Jama’atu Ta’awun Muslimeen, Sheik Daood Molaasan, jẹ oye Mufti Agba ilẹ Yoruba.

Lẹyin ti ọrọ naa di ariwo ni Oluwoo sọ pe Mufty agba ilẹ Iwo loun fẹẹ fi Mọlaasan jẹ bayii, ki i ṣe ti ilẹ Yoruba mọ.

Nigba to n gbe igbẹjọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Sikiru Ọkẹ paṣẹ pe olujẹjọ ko gbọdọ fi Mọlaasan, ẹni ti oun naa ni ẹjọ lati jẹ, jẹ oye naa.

Bakan naa ni kootu paṣẹ pe Mọlaasan ko gbọdọ pe ara rẹ ni Mufti Agba ilẹ Yoruba nibikibi titi ti kootu yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ọrọ naa.

Ni bayii ti eto naa ku ọla, Sheik Kewulere ti kilọ fun Oluwoo lati ma ṣe huwa to le mu un ṣaigbọran si aṣẹ ile-ẹjọ.

 

Kewulere sọ pe, gẹgẹ bii ọba, Oluwoo ko ni ạṣẹ tabi agbara lati fi ẹnikẹni jẹ oye ẹsin Musulumi bii Ọtun Ajanasi, Ajanasi, Mufti Agba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply