Dẹrẹba at’ọmọọṣẹ rẹ ku sinu ijamba ọkọ

Ismail Adeẹyọ

Awakọ kan, ati ọmọọṣẹ rẹ, tẹnikẹni ko tii mọ orukọ wọn lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, ni wọn ti kagbako iku ojiji lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ta wa yii, ninu ijamba ọkọ kan to waye l’opopona marosẹ Eko si Ibadan, ọkọ ajagbe kan ti nọmba rẹ jẹ EKY 65 XF to ko apo fulawa ti wọn fi n ṣe burẹdi, ni wọn lo bajẹ lọna, ti wọn si gbiyanju ati ti kuro loju ọna to wa, amọ niṣe ni ọkọ Peugeot J5 kan n sare bọ,  lo ba kọlu tirela ọhun nibi ti wọn paaki rẹ si, loju ẹsẹ si ni dẹrẹba ọkọ J5 yii ati ọmọ-iṣẹ rẹ ku, tawọn eeyan meji mi-in si fara pa gidigidi nibi iṣẹlẹ ọhun.

Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun soju rẹ ni, deede agogo mẹfa aabọ irọlẹ ni iṣẹlẹ laabi ọhun waye, lagbegbe ilu  Ṣapade, lọna marosẹ ọhun, nijọba ibilẹ Rẹmọ, ipinlẹ Ogun, ata ati tomato lọkọ J5 ọhun ko, ko too lọ sẹri mọ tirela ti wọn paaki sẹgbẹ titi jẹẹjẹ, ki dẹrẹba rẹ ati ọmọọṣẹ rẹ kan too da ẹmi ara wọn legbodo.

O ni wọn ti ko oku awọn mejeeji to doloogbe yii lọọ si ile igbokuu-pamọ-si to wa ni Ipara-Rẹmọ, wọn si ti ko awọn to fara pa naa lọ si ile-iwosan fun itọju.’’

Alukoro ẹṣọ ojupopo ipinlẹ Ogun, TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin ṣalaye pe, ere asapajude ti awakọ J5 ọhun sa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ibanujẹ yii, o ni ere ọhun ni ko jẹ ki awakọ yii le ko ijanu ọkọ rẹ nigba to yọ sibi ti wọn paaki ọkọ tirela naa si lojiji, ati pe ọkọ J5 ọhun ko ni nọmba lara.

O wa rọ awọn awakọ lati maa rọra sare l’ojupopo tori ẹmi o laarọ, bẹẹ lo kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn tọrọ kan pe Ọlọrun yoo rọ wọn lọkan. O lawọn ṣi n ṣewadii iṣẹlẹ yii. 

Leave a Reply