Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Dẹrẹba ni Oluwaṣeyi Oyetunde nileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Hayat Kimya, ni Agbara, ipinlẹ Ogun. Ṣugbọn o huwa ole lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, nigba to gbe ọja miliọnu mẹrin ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgberin naira ( 4.7m) lọ siluu Eko, ti ko si kowo wale fun ileeṣẹ to ran an lọ.
Nigba to di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ti ileeṣẹ ko gburoo dẹrẹba yii, ti wọn ko si ri i ko gbowo wale tabi da mọto pada, ni wọn fi to ọlọpaa leti l’Agbara, awọn iyẹn si bẹrẹ si i wa.
Nigba tawọn ọtẹlẹmuyẹ to n wa a yoo ri i, Eko ti ileeṣẹ ẹ ni ko gbe ọja lọ naa ni wọn ti mu un. Bi wọn ṣe mu un lo jẹwọ fun wọn pe oun ti ta ọja ti ileeṣẹ gbe foun lowo pọọku, oun si ti ko owo naa sapo oun.
Ninu alaye to ṣe siwaju ni Oluwaṣeyi ti sọ pe ẹnikan to n jẹ Ṣẹgun Oluwaṣeun ati Chijioke Ogbu, ni wọn ra ọja naa lọwọ oun lowo ti ko to nnkan.
Kia lawọn ọlọpaa ti lọọ mu awọn meji yii naa, wọn si ri diẹ gba pada lọwọ wọn ninu ẹru ole ti wọn ra ọhun.
Wọn ti ni wọn yoo gbe awọn mẹtẹẹta lọ si kootu laipẹ, nibi ti wọn yoo ti jẹjọ agbepolaja ati ẹni to gba a silẹ lọwọ rẹ.