Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ere to pọ ju ti awakọ bọọsi akero kan n sa nirọlẹ Ọjọbọ, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ yii, lo ran an lọ sọrun ojiji loju ọna marosẹ Abẹokuta s’Ibadan, gbogbo ero ọkọ ti wọn jẹ mẹtadinlogun to ko naa lo si balẹ sileewosan, nitori wọn fara pa gidi.
Ibi kan tl wọn n pe ni Kila, loju ọna yii ni mọto ti nọmba ẹ jé KRD 356 XJ ọhun de ti nnkan fi daru mọ ọn lọwọ.
Niṣe ni apa dẹrẹba ko ka ere ti wọn lo n sa bọ naa mọ, n lo ba la a mọ pepele oju ọna, ni mọto ba bẹrẹ si i takiti, nibi ti dẹrẹba naa ku si niyẹn, ti awọn ero ọkọ yooku si fara pa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣalaye pe nnkan bíi aago mẹrin irọlẹ ku iṣẹju meje ni ijamba yii waye.
O ni ọkunrin mejọ, obinrin mẹwaa, lawọn to wa ninu bọọsi naa.
Abẹokuta ni wọn n lọ gẹgẹ bi Akinbiyi ṣe wi, Ibadan si ni wọn ti n bọ ki dẹrẹba naa too maa sare buruku.
Akinbiyi sọ pe mọto kankan ko kọ lu bọọsi Hiace tijamba kan yii, awakọ rẹ lo n sare ju ti wahala fi ṣẹlẹ̀.
Awọn ẹbi dẹrẹba yii ti gba oku ẹ lọwọ ajo TRACE gẹgẹ bo ṣe wi, wọn ti lọọ sin in. Awọn ero to fara pa naa si ti wa lọsibitu kan ni Ọmi-Adio, nipinlẹ Ọyọ.