Florence Babaṣọla, Osogbo
Titi digba ti a n koroyin yii jọ, ileewosan ni awọn akẹkọọ marundinlogoji ti Fakunle Comprehensive High School, to wa lagbegbe Stadium, niluu Oṣogbo, ti wọn fori lugbadi tia-gaasi tawọn ọlọpaa yin laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii wa.
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa kogberegbe Mopol 39 Base, ti agọ wọn wa nitosi ileewe naa ni wọn n ṣere idaraya alaraarọ ti wọn maa n ṣe lati gbaradi fun iṣẹlẹ pajawiri.
Nibẹ ni wọn ti yin tia-gaasi soke, ṣugbọn ti afẹfẹ gbe eefin naa lọ sinu ileewe Fakunle. Bayii lawọn akẹkọọ kọọkan bẹrẹ si i hukọ, ti awọn mi-in si daku.
Kiakia lawọn ọga wọn pe awọn oṣiṣẹ itọju pajawiri, O’Ambulance, ti wọn si ko awọn akẹkọọ naa lọ sileewosan, wọn ko awọn kan lọ si ọsibitu to wa nitosi ileewe yii, wọn si gbe awọn kan lọ si OSUNTHC.
Oju-ẹsẹ ni wọn ti paṣẹ fun awọn akẹkọọ yooku lati maa lọ sile wọn, ṣugbọn nigba tawọn miiran dele ni eefin ti wọn ti fa simu naa too fara han, ti wọn si gbe awọn naa lọ sọsibitu.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, tọrọ aforijin lọwọ awọn ti wọn lugbadi iṣẹlẹ naa.
O ni idaraya araarọ ti wọn maa n ṣe lawọn ọlọpaa kogbere naa n ṣe, ati pe iru rẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ.