Dokita da Igbakeji Aarẹ ilẹ wa duro sọsibitu

Jọkẹ Amọri

Lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, ileewosan ni Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, wa, nibi tawọn dokita da a duro si, ti wọn si n ṣayẹwo igbesẹ to yẹ lori iṣẹ abẹ ti wọn feẹ ṣe fun un.

Ẹsẹ kan la gbọ pe o n dun ọkunrin naa, latari bọọlu alásẹ́ to maa n gba, nitori o ṣeṣe nibẹ. Nigba ti ẹsẹ naa si kọ ti ko lọ, to n fi gbogbo igba dun un ni Ọṣinbajo lọọ ri awọn dokita rẹ. Abajade rẹ ni pe o ṣee ṣe ki wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un lori ẹsẹ naa. Ṣugbọn dokita rẹ ṣi n wo o loju na gẹgẹ bi Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Laolu Akande, ṣe sọ.

Ninu ọrọ to gbe sori ikanni twitter lo ti kọ ọ pe, ‘‘Igbakeji Aarẹ lọ si ileewosan lonii fun igbesẹ lati ṣe iṣẹ abẹ. Eyi ko sẹyin ẹsẹ to n dun un ti ko si lọ naa nitori pe o ṣeṣe lasiko to n gba bọọlu alasẹ. Dokita rẹ yoo sọ ibi ti wọn ba ba ọrọ de lori itọju rẹ lonii’’. Bẹẹ ni Laolu pari ọrọ rẹ.

Leave a Reply