Dokita yii n rin ni bebe ẹwọn o, mita ina lo ji l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

 

 

 

Dokita kan ati ọmọọṣẹ rẹ ti wọn fẹsun kan pe wọn ji mita ina ileeṣẹ IBEDC niluu Oṣogbo ni wọn ti foju bale-ẹjọ Majisreeti l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Awọn olujẹjọ mejeeji ọhun; Olajumọkẹ Tokunbọ, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ati Oyinlọla Oluwatosin, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ni wọn huwa naa laarin ọjọ kẹtadinlọgbọn, osu kin-in-ni, ọdun yii, si ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta.

Sajẹnti Adeoye Kayọde to jẹ agbefọba ṣalaye ni kootu pe lagbegbe Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo, ni ọsibitu awọn olujẹjọ naa wa. O ni ṣe ni wọn pawọ-pọ ji mita ina to ni nọmba 14313649, ti owo rẹ si jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira (#250,000).

Adeoye fi kun un pe ṣe ni Ọlajumọkẹ gbe ija ko awọn oṣiṣẹ IBEDC; Paul Taiwo Ishọla, Kehinde Fashakin ati Ibrahim Lawal, loju lọjọ ti wọn lọ sibẹ, to si fi mọto rẹ dina ki wọn ma baa raaye wọle.

Gbogbo akaba (ladder) atawọn irinṣẹ ti wọn ko lọ sibẹ lọjọ naa lọkunrin naa fọn danu, to si gba awọn ajọ Sifu Difẹnsi lọpọlọpọ wakati ki wọn too ṣeto alaafia pada sagbegbe naa.

Lẹyin ti awọn olujẹjọ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun mẹfẹẹfa ti wọn fi kan wọn ni agbẹjọro wọn, Sunday Abọlade, rọ kootu lati fun wọn ni beeli lọna irọrun.

Onidaajọ A. A. Adeyẹba fun wọn ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) ati oniduuro kan ni iye kan naa.

O sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun yii.

Leave a Reply