Ẹṣọ alaabo mu awọn Fulani darandaran to ya wọ  Kwara lọna aitọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo, ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, pẹlu ajọṣepọ ọmọ ologun ati ileeṣẹ ọlọpaa, ti mu awọn Fulani darandaran pẹlu awọn maaluu wọn, ni Ẹrinle si Ọffa, latari pe wọn wọ ipinlẹ naa lọna aitọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, Babawale Zaid Afolabi, fi lede ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti sọ pe ajọ naa pẹlu ajọṣepọ ọmọ ologun ati ọlọpaa ti mu awọn afurasi Fulani darandaran pẹlu awọn maaluu wọn ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lagbegbe ilu Ẹrinle si Ọffa, ti wọn si ni ilu Ajaṣẹ-Ipo, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ni awọn n lọ fun ibujoko ayọ, ti awọn ẹsọ alaabo si tẹle wọn de ilu Ajaṣẹ-Ipo ti wọn n lọ fun ayẹwo finni-finni ati ẹkunrẹrẹ iwadii.

Leave a Reply