Ẹṣọ Amọtẹkun gbẹsẹ le ọgọrun-un maaluu to lu ofin ijọba ipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Maaluu bii ọgọrun-un kan lawọn ẹṣọ Amọtẹkun ti gbẹsẹ le lori ẹsun ṣiṣe lodi sofin ijọba ipinlẹ Ondo, eyi to de kiko ẹran jẹ nita gbangba.

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ni ọwọ tẹ awọn maaluu ọhun ni aala ipinlẹ Ondo ati Ọṣun loju ọna marosẹ Akurẹ si Ileṣa.

O ni ṣe lawọn Fulani ọhun fi awọn maaluu ti wọn n da di oju ọna marosẹ yii pa, ti wọn ko si jẹ ki ọkọ atawọn arinrinajo to rin si asiko iṣẹlẹ naa raaye kọja fun ọpọ iṣẹju.

Yatọ si ti ofin ijọba, eyi to de kiko ẹran jẹ lai gba aṣẹ tawọn Fulani ọhun ṣe lodi si, o ni ohun ti wọn ṣe ọhun tun jẹ ọna kan pataki tawọn darandaran n lo lati da awọn arinrinajo lọna fun idigunjale tabi ijinigbe.

Ọkan ninu awọn awakọ to ha si aarin ọna lọjọ naa lo ni o sare pe awọn sori aago, ti awọn si ri i daju pe awọn debi iṣẹlẹ naa laarin ọgbọn iṣẹju pere.

O ni bi awọn Fulani naa ṣe ri awọn ẹsọ Amọtẹkun ni wọn fẹẹ maa sa lọ, ṣugbọn awọn ri i daju pe awọn gba ọgọrun-un maaluu silẹ lọwọ wọn, ti awọn si tun fi panpẹ ofin gbe mẹsan-an ninu awọn darandaran ọhun.

Awọn maaluu ọhun lo ni awọn ko lati ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye lọ si ọfiisi awọn ni Alagbaka, niluu Akurẹ, eyi to to bii ọgbọn ibusọ.

Adelẹyẹ ni kawọn eeyan lọọ fọkan balẹ, nitori pe gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo lawọn ni ọfiisi atawọn oṣiṣẹ si.

Eyikeyii ninu awọn ọfiisi naa lo ni awọn araalu le kan si nigbakuugba ti ohunkohun ba n ṣẹlẹ lagbegbe wọn.

 

 

Leave a Reply