Faith Adebọla
Bo ṣe ku ọjọ perete tawọn ọmọ Naijiria yoo jade dibo lati yan aarẹ mi-in ti yoo tukọ iṣakoso orileede yii lẹyin tijọba Muhammadu Buhari ba tẹnu bọpo ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, ọrọ amọran to da bii ikilọ ti jade lati ẹnu Oludasilẹ ijọ Living Faith Church, tawọn eeyan n pe ni Winners’ Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo, pe kawọn eeyan ṣe laakaye, ki wọn mọru ẹni ti wọn fẹẹ tẹka fun, o ni wọn ko gbọdọ yan oloṣelu to maa mu wọn lẹru tabi ti wọn ko mọ ipilẹṣẹ ọla ati owo rẹ, tori inira mi-in ni wọn tun fẹẹ kọwe si yẹn.
Ojiṣẹ Oluwa yii sọrọ ọhun ninu iwaasu rẹ nibi eto ijọsin to waye ni ṣọọṣi naa to wa ni Cannanland, ilu Ọta, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji yii.
Oyedepo ni oun rọ awọn ọmọ ijọ oun, atawọn eeyan orileede yii lati yan ẹni to niwa rere, to lokun ati agbara, ẹni to dangajia, to si jẹ ọmọluabi ati oloootọ sipo.
O ni: “Ko digba teeyan ba di bilọnia ko too le jẹ aarẹ, ohun ta a nilo ni okun ati agbara, iwa ọmọluabi, jijẹ oloootọ, iru awọn eeyan bẹẹ ṣi wa kaakiri orileede yii.
“Oludije to maa mu ilọsiwaju ba orileede yii ni kẹ ẹ dibo yin fun, ẹni ti yoo mu ki Naijiria sunwọn fẹyin, awọn ọmọ yin, atawọn ọmọ ti ẹ ko ti i bi ni kẹ ẹ yan sipo.
“Mo mọ pe awọn ọmọ-ijọ yii wa kaakiri ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ, tori ẹ, ki i ṣe iwaasu ẹgbẹ oṣelu ni mo n ṣe. Mo fẹ ki ẹ jẹ oloootọ si Ọlọrun ju ẹgbẹ oṣelu eyikeyii lọ. Ẹ ma dibo fawọn ika. Ẹ ma dibo fawọn tẹ o mọ orisun owo ati ọla wọn. Ẹ ma si dibo fawọn ti wọn maa ṣeleri ohun ti wọn fẹẹ ṣe fun yin, ṣugbọn ti ẹ ko le ri ohun aritọkasi gidi ti wọn ti ṣe sẹyin nawọ si. Ẹ ranti pe awọn ti wọn wa nipo lasiko yii ṣe ọkan-o-jọkan ileri kọngbẹ-kọngbẹ fun wa, ti wọn ni tawọn ba wọle, awọn aa dogun, awọn aa dogoji, awọn aa soke dilẹ, ṣugbọn ko si ẹyọ kan ṣoṣo pere ninu awọn ileri wọn ti wọn muṣẹ. Ileri ofo ni wọn ṣe. Ṣe iru awọn ileri asan bẹẹ lẹ tun fẹẹ gbọkanle lasiko yii, iwa omugọ gbaa niyẹn maa jẹ o.
“Gbogbo wa la ri ohun to ti n ṣẹlẹ lorileede yii lati bii ọdun mẹjọ sẹyin. Tẹ ẹ ba tun lọọ ṣatilẹyin fawọn ika ẹda, tabi tẹ ẹ kaaanu wọn, a jẹ pe ika lẹyin naa niyẹn.
Ẹ ma jẹ ko ya yin lẹnu idi ti ọrọ yii fi ka mi lara to bẹẹ o. O ka mi lara nitori alaafia ati ifọkanbalẹ Naijiria jẹ mi logun ni. Ko yẹ ka jẹ ki wọn lu aago gbanjo le Naijiria lori. A o ki i ṣe dukia tabi nnkan eelo ti wọn le lu ta ni gbanjo, eeyan ni wa, eeyan ti ko ṣee diye le.”
Baba agbalagba naa kadii ọrọ rẹ nilẹ pe ko ṣoro lati da awọn eeyan ti wọn le tun orileede yii ṣe mọ, yatọ sawọn ẹlẹtan ati onijibiti. O ni ipo aarẹ ki i ṣe ogun ibi ẹnikan, ki i ṣe dukia ẹnikẹni, bẹẹ si ni agbegbe kan tabi ẹya kan ko lẹtọọ si i ju awọn to ku lọ.