Ẹ ba mi bẹ wọn ki wọn ma pa baba yii fun mi

Mo n wa oogun ti mo maa maa fun Alaaji lo, oogun ti ko ni i jẹ ki aarẹ mu un. Nitori gbogbo eyi ti a n wi yii dun, Ọlọrun ko ni i jẹ ka ri aarẹ, iṣọwọ tawọn obinrin yii fi n lo o, bi wọn ṣe n lo Alaaji yii, ko si ki wọn ma kọ ile aarẹ si i lara. Emi o si ni i gba, nitori n oo ni i jẹ ki wọn pa ọkọ mi fun mi. Bi ko si jẹ ti ija oun naa to ṣoroo gbe ni, n ba mọ ohun ti n ba ṣe. Alaaji ko lagbara wahala ti wọn n ko o si yii, tabi eyi toun naa n ko ara ẹ si yii, ọjọ ori ẹ ti ju bẹẹ lọ, ṣugbọn o ti wọ ọ o ti wọ ọ na, bi ọrọ naa ko ṣe waa ni i di abamọ fun emi lo ku ti mo n ṣe.

Ṣe ẹ mọ pe wahala ọrọ ọjọ yẹn ko ti i tan nile wa, wahala ọjọ ti mo waa sọrọ ile fun wọn, ti mo si ra waini fun wọn lati mu, ti Safu fi mu Alaaji wọle, to lọọ tilẹkun mọ ọn. Ọrọ naa ko ti i tan. Bi a ba fẹẹ sọ tootọ, Safu lo lọkọ, oun ni iyawo kekere, oun ni wọn si jọ n gbe, ko sẹni to yẹ ko maa ba a du u ni iru alẹ ọjọ nnkan ẹyẹ bẹẹ yẹn. Oun ni wọn ṣaa jọ n sun, oun ni wọn jọ n gbe inu yara kan naa, asiko to si fẹ ki ọkọ ẹ waa sun lo mu un wọ inu ile yẹn. Ko kuku le wa ni palọ, ko ni ka ma ṣere tiwa, ọkọ ẹ lo mu wọle. Bo ba jẹ emi naa, mo le ṣe ju bẹẹ lọ.

Awọn iyawo Alaaji to ku ko le mu un mọra ṣaa, afi Iyaale wa agba nikan. Ọrọ naa ka Iya Dele lara to jẹ laaarọ kutu lo ti waa ji ka mi mọ oke, mo ṣẹṣe ki Asubaa tan ni. Lo ba de lo le furukọkọ, loju ẹ le koko, laaarọ kutu! Emi si ti mọ bi mo ṣe n mu un walẹ bo ba ti ri bẹẹ yẹn, paapaa lọwọ ti mo wa yii, ọwọ ti mo wa yii ko ba ẹni kan ja, igberaga ni wọn maa ka a si. Niṣe ni mo ni, “Sista mi! Aunti mi ti o baadi! Ṣe ki i ṣe pe ẹnikan ti ji ọkọ yin gbe lọ, abi ki lo de toju le bayii!” Nigba yẹn lo too tuju ka diẹ, ṣugbọn ko ti i rẹrin-in rara.

Lo ba ni, ” Ẹjọ ọmọ rẹ ni mo waa fi sun ẹ, nitori iwọ ni iya kereni to b’Ido, iya bo ti n sin lọmọ n ja bọ, beeyan o ba rọmọ ri gan-an, ko gbọdọ le ju tiẹ yii naa lọ. Ṣaa ba emi kilọ fun un ko ma ṣe mẹẹsi ẹ de ọdọ mi!” Bi inu ba ti bi Iyaale mi tan lawọn oyinbo igilariti bayii maa n jade, ko ma ṣe mẹẹsi! Lemi naa ba ju u lu u, mo ni mẹẹsi wo lọmọ mi ṣe fun yin ti ẹ ẹ le sọ fun mi ki n tete ba a wi. Lo ba ni ki i ṣe ọrọ ere loun n sọ o, pe ṣe mi o ri i bo ṣe ṣe fawọn lanaa ni, to tilẹkun mọ awọn, to lọọ ha Alaaji mọle, ṣe oun nikan lo lọkọ ni, abi ki i ṣe awọn kan lo ba niwaju!

Ọrọ naa waa ye mi patapata. Nnkan ti mo laiki Iya Dele si niyẹn, oun ki i pe aja lọbọ, ko ni i fi ọrọ si abẹ ahọn sọ, bi ọrọ ba ti ri lo maa la a mọlẹ. Nigbaa ti mo ri i bi ọrọ naa ti dun un to, mo waa sun mọ ọn, mo ni, ‘Aunti mi, ẹ ti n gbagbe ọjọ. Ṣe ẹyin naa ko ṣe ju bayii lọ ri, nile Alaaji yii kan naa, abi ki n ran yin leti ni. Abi ẹ ti gbagbe ọjọ kan bayii tẹ ẹ le Iyaale wa agba jade, tẹ ẹ ni kemi naa ba ara mi da sọhun-un, ẹyin loorun kan, lọjọ Ileya kan bayii!’ Lo ba ni, ‘’Igba naa nkọ! Ṣe ohun ti o wa n sọ fun mi bayii ni pe ẹsan lo n ke, abi kin ni itumọ itan too bẹrẹ si i sọ yií’’

Mo ni ko ri bẹẹ, mo kan fẹ ko mọ pe awa naa ti ṣe bẹẹ ri ni. Mo ni ṣe o mọ pe n ko jẹ tan an, n ko jẹ parọ fun un. Mo ni ṣe ko mọ  pe bi ko ba mu Alaaji bo ṣe mu un lalẹ ana yẹn, Aunti Sikira lo maa ki baba mọlẹ, ki la waa fẹẹ ṣe to ba ki i !’ Nigba yẹn loju ẹ tuka, inu ẹ tiẹ dun si ohun to ṣẹlẹ, ko fẹran Aunti Sikira rara. O ni o tiẹ tẹ oun lọrun pe Safu lo fa Alaaji wọle loootọ, pe nitori eletekete obinrin kan ni Sikira yẹn, ko si lojuti, ko si tun bẹru ẹni kan, ohun to ba fẹẹ ṣe lo maa ṣe, bẹẹ kinni ọhun ko ni i daa. Nibẹ lọrọ tiyẹn pari si.

Ṣugbọn o sọ fun mi o, o ni ṣe mo mọ pe ki i ṣe ibẹ yẹn ni ọrọ toun pari si ṣaa, ṣe mọ mọ pe ọti ti mo ra yẹn ki i ṣe foun, oun kan ba awọn eeyan fi iyẹn ṣe faaji ni o, owo loun fẹ ni toun, oun fẹẹ pada si ṣọọbu, koun naa tiẹ maa ri nnkan kan ta koun yee jokoo sile, pe lati igba ti oun ti gbe ṣọọbu tọki yẹn silẹ, oun ko ri nnkan mi-in ṣe mọ, gbogbo owo ti oun iba si maa ri gba lọwọ Dele, o ni owo ko si ni idi iṣẹ ṣọja to bẹẹ, iwọnba to si n ri, oun atiyawo ẹ ni wọn jọ n na an. O ni ṣe mo mọ pe ọmọ ti wọn bi to ṣẹṣẹ le lọdun, wọn ti fi i sileewe olowo nla!

Mo ni ko fi wọn silẹ ko jẹ ki wọn maa ṣe aye wọn, pe ohun to ba fẹ ni ko sọ femi, ko fi Dele ati iyawo ẹ silẹ. O loun ti mọ, oun ti mọ pe emi ni iya ẹ, oun ti mọ pe ẹyin Dele lemi maa wa, nitori ẹ loun o ṣe fẹẹ sọrọ ẹ fun mi. O ni ko kuku tiẹ kan oun o, ki emi ṣaa gba ṣọọbu foun, ki n si ko ọja si i, o ti tan, igba yẹn ni mo ṣẹṣẹ wẹ ile ti mo ra l’Oṣodi foun, ṣugbọn ti oni-waini yẹn, Sikira lemi ṣe iyẹn fun o. Emi o sọ fun un pe o ti wa lọkan mi lati fun wọn lowo tẹlẹ o, nigba to si jẹ oun lo fẹnu ara ẹ sọ ọ yii, inu mi dun. Mo ni ko lọọ wadii iye ti ṣọọbu ati ọja inu ẹ maa jẹ.

Mo n reti ki Safu waa dagbere fun mi, aṣe o ti lọ si ṣọọbu tipẹtipẹ, ni gbogbo igba ti Iya Dele fi wa lọdọ mi yẹn loun ti lọ. Igba ti mo reti ẹ ti mi o ri i lemi naa ba mura. Bi mo ṣe sọkalẹ pe ki n lọọ dagbere fun Iyaale wa agba, ki n si na ohun pe Safu, bẹẹ ni mo  gbọ ariwo lati inu yara Aunti Sikira, ‘A lo ti rẹ mi! Jẹ ki n sinmi diẹ! N oo kuku lọ sibi kan, a jọ wa lati aarọ dalẹ ni!’ Bi mo ṣe gbohun yẹn ni mo ṣe mọ pe ohun Alaaji ni. Ki lo n wa nibi, ṣe o fi Safu sinu ile o tun waa ba Aunti Sikira ni! N ko tiẹ mọ eyi to n bi mi ninu nibẹ, niṣe ni mo da atẹwọ bo ilẹkun ẹ!

Wọn o kọkọ dahun, igba ti mo tun gba a lẹekeji ti mo pariwo, Aunti Sikiraa! Aunti Sikiraa! Lo ba ṣilẹkun, lo ba ranju mọ mi, ẹrin lo n rin, were kan lọmọbinrin yẹn. O ni, “Iyaa wa, olowo inu famili, Ọlọrun ti ri wa ko too da ẹ saarin wa, mo n bọ waa gba ẹtọ temi lọwọ ẹ. Owo wa lọwọ ẹ, oo baa jẹ iyaale mi ju bẹẹ lọ, aburo mi ni ẹ, mo ju ẹ lọ lọjọ ori, soo, ko o ti mọ pe mo n bọ waa gba ẹto temi, nitori mi o ki i ṣe ọmuti, owo lemi naa fẹ. Ṣugbọn lọwọ ti mo wa yii, ounjẹ ti ọmọ to o mu wale ko jẹ ki n jẹ lanaa, mo fẹẹ jẹ temi bayii!’ Afi gbaga to tilẹkun!

Iyaale wa agba ni wọn yọju pe ki n tete maa lọ sibi iṣẹ ni temi o, ki n ma jẹ ki wọn fi tiwọn da mi duro, wọn ni Safu ma ti lọ ni tiẹ tipẹ o, igba to lọ tan ni Sikira lọọ wọ Alaaji jade to tilẹkun mọ ọn! Abi iru ki lọkọ mi waa ko ara ẹ si yii! Ki wọn ma pa baba yii fun mi o.

Leave a Reply