Jọkẹ Amọri
Inu n bi iyawo gomina ipinlẹ Ondo, Arabinrin Anyanwu Akeredolu gidigidi. Ibinu naa ko si sẹyin ọmọbinrin kan ti ko fi ọkọ rẹ lọrun silẹ. O ni agbo atawọn oogun ibilẹ loriṣiiriṣii lo n gbe wa fun un lori aisan to n ṣe e, oun si ti sọ fun un ko yee gbe awọn agbo yii wa fun ọkọ oun, ṣugbọn ko gbọran. Beẹ lo bu ẹnu atẹ lu bi ọmọbinrin ti wọn pe ni Bunmi Ademosun ọhun ṣe n wa gbogbo ọna lati di igbakeji gomina bi ohunkohun ba ṣe ọkọ oun.
Iyawo gomina yii ti waa kilọ fun ọmọbinrin naa pe ko jinna si ọkọ oun o, bo ba si kọ ti ko jinna si i, ohun to n wa nidii iṣukọ, yoo ri i nidii ewura, nitori gẹgẹ bii obinrin to wa lati ilẹ Ibo, oun ko ni i mu ọrọ naa ni kekere pẹlu rẹ, gbogbo ohun ti oun ni loun ma fi ba a ja. Ninu fọnran to gbe jade naa to n ja ran-in lori ayelujara to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti sọ pe, ‘‘Ẹ kaaarọ o, gbogbo eeyan, emi ni Arabinrin, mo ni iṣẹ kan lati jẹ fun Ademosun, mo gbagbọ pe o wa ninu ẹgbẹ ti wọn n pe ni Aketi Women’s Platform yii. N ko ni nọmba rẹ, n si ro pe o yẹ ninu ẹni to yẹ ki n ni nọmba rẹ. Mo fẹẹ kilọ fun obinrin yii ko fi ọkọ mi silẹ o. Ko yee yọ waa gbe awọn agbo, oogun ibilẹ oriṣiiriṣii to n ṣọ pe oun gba latọdọ awọn pasitọ rẹ, awọn ayederu pasitọ rẹ lati fun ọkọ mi lati mu. A gbagbọ ninu oogun oyinbo, a gbagbọ ninu itọju igbalode, a si gbagbọ pe ara Aketi maa ya.
‘‘Ṣugbọn ohun to mu iṣẹ ti mo n ran si i yii wa ni awọn oogun to tun n gbe wa fun ọkọ mi lẹnu ọjọ mẹta yii. Jinna si ọkọ mi o, jinna si Aketi o. Fun igba ikẹyin, mo n kilọ fun ọ o, Ademosun, jinna si Aketi o. Jinna si ọkọ mi, ki o si yee yọ waa gbe awọn agbo buruku ti o n gbe kiri yii wa fun un lati mu. Ohun ti oju rẹ maa ri, o ko ni i le ka a tan o. Gẹgẹ bii obinrin Ibo, lori ohun to ba jẹ mọ bayii, n ko ni i mu un ni kekere pẹlu rẹ, ohun ti ma a ṣe fun ọ, o ko ni i gbagbe laelae nile aye rẹ. Fun igba ikẹyin ni mo n sọ fun ọ, Ademosun abi ki lo pe orukọ rẹ, jinna si Aketi o, yee gbe awọn agbo buruku ti o n gbe kiri yii wa fun ọkọ mi lati mu. Jinna si Aketi o, iwọ obinrin yii. O o ni i le ka ohun ti ma a ṣe fun ọ tan. O o ni i le ka a tan laye rẹ. Eeyan buruku aye atọrun ni ẹ, ma a lọ, ko o lọ jẹgbadun owo ti o ri. Gbogbo ohun ti mo ni ni ma a fi ba ẹ ja gẹgẹ bii obinrin Ibo. Mo si n kilọ fun ọ fun igba ikẹyin pe ki o jinna si ọkọ mi.
‘‘Jẹ ki n sọ fun ọ, gbogbo ipade oru to o n ṣe kiri, to o ni o fẹẹ jẹ igbakeji gomina Ondo, wo ara rẹ, ki lo wa lọpọlọ rẹ to o le fi ṣakoso ijọba lati di igbakeji gomina Ondo, Bi ohunkoun ba tilẹ waa ṣẹlẹ si Aketi, Lucky lo maa gbakoso ipo gomina, nitori o wa labẹ ofin bẹẹ. Ṣugbọn ki o maa waa dọgbọn kiri, ki o maa dọgbọn pe o fẹẹ ṣe igbakeji gomina, hunn.
‘‘Mo kilọ fun Aketi latilẹ pe obinrin yii ko daa, mo sọ fun un pe eeyan buruku, eeyan ibi ni obinrin yii. O si ti n ṣẹlẹ bẹ ẹ. Mo sọ pe ko ni ohun to dara fun ọ, mo kilọ fun ọ. Ibi gidigidi ni obinrin yii. Mo si n kilọ fun ọ fun igba ikẹyin pe ki o jinna si ọkọ mi.
‘‘Jẹ ki n sọ fun ọ, ti o ba n ba obinrin Ibo ṣe niru nnkan bayii, mo maa kọ ọ ni ẹkọ ti o ko ni i gbagbe laye rẹ. Bi iyawo gomina ipinlẹ Ondo, Betty Anyanwu, ṣe sọrọ naa pẹlu ẹdun ọkan ati ibinu ree.
Ṣe o ti ṣe diẹ ti awọn eeyan ti n gbe e kiri pe ara Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, yii ko ya. Asiko kan si wa ti o kuro nile ijọba, to lọọ gba itọju fun bii oṣu mẹta, bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọlẹyin rẹ sọ nigba naa pe ko sohun to ṣe e, ati pe ilu Abuja lo wa.
Ṣugbọn awọn to ri gomina naa lẹnu ọjọ mẹta yii ni ọkunrin naa ti ru gan-an, o si han loootọ pe aisan kan n ba gomina yii finra lagọọ ara rẹ.
Ṣa, iyawo gomina yii ti sọ pe bi ohunkohun ba ṣe ọkọ oun, Bunmi Ademosun ni ki wọn lọọ mu. ALAROYE gbọ pe Oludamọran pataki si Aketi ni obinrin yii.