Stephen Ajagbe, Ilọrin
Lọna ati bu ọla fun ogbontarigi agbabọọlu ilẹ wa to ti doloogbe, Rashidi Yẹkini, ati lati maa ṣeranti rẹ, Aarẹ ajọ to n ṣakoso ere bọọlu lorilẹ-ede Naijiria, Amaju Pinnick, ti rọ Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lati fi orukọ agbabọọlu naa sọ papa iṣere to wa niluu Ilọrin yii.
Pinnick sọrọ naa lasiko to ṣe abẹwo si gomina nile ijọba l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
O ni Yẹkini kopa ribiribi ti ko si ṣee gbagbe fun orilẹede yii, o fi gbogbo aye rẹ jin lasiko to n gba bọọlu fun Naijiria, nitori naa, o ṣe pataki lati fi nnkan ṣe iranti rẹ, paapaa ju lọ bi oloogbe naa tun ṣe jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara.
Pinnick wa si Kwara lati kopa nibi ayẹyẹ ṣiṣi ile bọọlu ti wọn n pe ni ‘Football House’, eyi tijọba Kwara ṣẹṣẹ kọ to jẹ akọkọ iru ẹ lorilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina Abdulrazaq fi idaniloju han pe ijọba yoo san oore ipa ti Rashidi ko fun orilẹ-ede yii.
Abdulrazaq ni, “A ko gbagbe Rashidi Yẹkini o. A ti n ṣeto ba a ṣe maa ohun meremere ati ohun to dara lati ṣe iranti rẹ.”
Ile bọọlu tijọba ṣi naa ni Abdulrazaq fi sọri Wali tilu Ilọrin, Alhaji Usman Mustapha, fun ipa to fi lelẹ nipinlẹ naa.
O ni ibudo naa yoo mu idagbasoke ba ere idaraya nipinlẹ Kwara.
Kilo maa n fa ti won ki n ma nrati awon akoni wa won yii nigba ti won ba wa laye to je wipe odigba ti won ba ku ki won to maa ranti tabi mo riri won, tori agbo bi iya se je arakunrin yii koto di wipe ku la n gbo iroyin. Sungbon sa fun eleyi tiwon se yii ohun to dara ni ti gomina ipinle naa ba le fowo so.