Ẹni kan to ku ninu ọkọ-ofurufu to jabọ lEkoo lanaa naa ti ku o

Awọn mẹta ni wọn wa ninu ọko ofurufu agberapaa (hẹlikoputa) to jabọ saarin ile meji lagbegbe Ọpẹbi lanaa ọjọ Ẹti, Furaide, lẹsẹkẹsẹ ni meji si ti ku ninu wọn. Wọn sare gbe ẹni kan to ku lọ si ọsibitu boya oun ko ni i ku, ṣugbọn nigba tiyoo fi di ọwọ alẹ, oun paapaa ti jẹ Ọlọrun nipe. Bẹẹ lawọn mẹtẹẹta ti wọn wa ninu ẹronpileeni kekere naa ku pata.

Ilu Pọta ni baaluu naa ti n bọ, Eko naa lo si wa, afi bo ṣe de agbegbe Ikẹja to ja si pàlàpálá ara ogiri ile 16A Salvation Road, Ọpẹbi. Nigba tawọn agbanila yoo si fi dedii ẹ, meji ti ku ninu awọn ti wọn wa nibẹ, oṣiṣẹ ileṣẹ to ni ọko-ofurufu naa ni gbogbo wọn. Ẹni kẹta to ṣi n mi ni wọn sare gbe lọ sọsibitu, afi bi iroyin ṣe sọ pe oun naa ti ku.

Agbẹnusọ ẹka to maa n wadii ijamba baaluu bayii, Ọgbẹni Tunji Oketunmbi, sọ pe bi ọrọ naa ṣe ri niyi, awọn mẹtẹẹta to wa ninu ọkọ agberapaa naa ti ku, ati pe awọn wa lẹnu iwadii ọrọ naa lati mọ ohun to fa sababi ti ẹronpileeni naa fi ja bọ.

Leave a Reply