Jide Alabi
Ki awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ma baa ko sọwọ awọn onijibiti ti wọn n fi eto ẹyawo parọ fun araalu, ijọba ti ni ki awọn eeyan ṣọra lati ma ṣe ko sọwọ gbaju-ẹ.
Lọjọ, Aje, Mọnde, ni wọn gbe ikede yii sita fun awọn araalu lati ṣọra pẹlu awọn ileeṣẹ kan ti wọn n parọ faraalu pe awọn le ya wọn lowo, nitori jibiti ni pupọ ninu wọn n fi eto ọhun lu, ti wọn ko si ni iwe aṣẹ ijọba.
Kọmiṣanna feto iroyin, Ọgbẹni Akin Ọmọle, lo sọrọ yii niluu Ado-Ekiti, nibi to ti sọ pe owo tawọn ọlẹdarun yii ko ni lọwọ ni wọn n parọ pe awọn fẹẹ ya araalu, bẹẹ ọgbọn lati lu wọn ni jibiti ni.
Lati le fidi ọrọ ẹ mulẹ lo mu un ṣapejuwe fidio awọn obinrin kan to n lọ kaakiri ẹrọ ayelujara bayii ti awọn eeyan kan ti lu ni jibiti.
O ni iṣẹlẹ ọhun jẹ nnkan to ba ni lọkan jẹ, bẹẹ ni inu ijọba ipinlẹ Ekiti paapaa ko dun si i rara. Kọmiṣanna ni kiru iṣẹlẹ bẹẹ ma baa waye lo mu ijọba gbe eto ẹyawo kalẹ fawọn eeyan nipinlẹ Ekiti, eyi ti yoo fun awọn oniṣowo keekeeke atawọn oniṣẹ ọwọ lanfaani lati ri owo gba, ti wọn yoo si maa san an pada lọna ti ko ni i ni wọn lara.
Ọmọle waa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti wọn ba fẹẹ yawo lati tọ ileeṣẹ ijọba to n mojuto okoowo ati ọrọ aje lọ lati ṣewadii iru eto ẹyawo ti wọn ba fẹ. Bakan naa lo ni ki wọn yago fawọn ileeṣẹ to le fi eto ẹyawo awuruju lu wọn ni jibiti owo wọn.