‘Ẹ fura o, awọn kan ti fẹẹ maa fi orukọ EFCC lu araalu ni jibiti ni Kwara’

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, ẹka ti Kwara, ti ke si awọn araalu lati ṣọra fawọn eeyan to n pe ara wọn ni aṣoju EFCC, ti wọn si n kaakiri ile awọn eeyan pataki lawujọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin wọn,Wilson Uwujaren, fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ti tẹ ẹ mọ awọn eeyan leti pe awọn kan n pe ara wọn ni aṣoju (Ambassador) EFCC, o ni ko sohun to jọ bẹẹ rara.

Uwujaren ni EFCC mọ riri atilẹyin awọn eeyan ninu igbogun tiwa jibiti ati ibajẹ, ṣugbọn o, nilẹ to mọ yii, ko si ẹnikẹni ti ajọ naa yan gẹgẹ bii aṣoju rẹ, nitori naa, ki awọn araalu ma jẹ kawọn eeyan kan fi orukọ EFCC lu wọn ni jibiti.

EFCC waa ṣekilọ fawọn to n lo orukọ wọn lati maa fi wọle sawọn eeyan jankan jankan ni Naijiria lara lati jawọ kia, bi bẹẹ kọ, wọn yoo kan idin ninu iyọ tọwọ ba tẹ wọn.

Wọn ni awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to ba nifẹẹ si igbelarugẹ ipolongo ta ko iwa ibajẹ ati jibiti le maa ṣe e lai lo orukọ EFCC tabi pe ara wọn ni aṣoju ajọ naa.

Leave a Reply