Faith Adebọla
Ajọ to n gbogun ti itankalẹ arun lorileede yii (Nigeria Centre for Disease Control) ti kede pe ẹya kan lara ẹrujẹjẹ arun aṣekupani nni, Koronafairọọsi, ti wọn n pe ni Omicron, ti gbọna ẹburu wọ orileede wa, wọn leeyan meji lo ti lugbadi ẹ bayii.
Omicron yii ni ẹya tuntun tawọn onimọ iṣegun ṣẹṣẹ ṣawari ẹ, lara awọn ẹya arun Korona, wọn loun lo buru ju awọn ẹya to ti jade tẹlẹ lọ, o si lewu gidi.
Atẹjade kan latọdọ ajọ NCDC, eyi ti Ọga agba ajọ naa, Dokita Ifẹdayọ Adetifa, fi lede lafẹmọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu kejila yii lo fidi ẹ mulẹ.
Atẹjade naa ka lapa kan pe:
“Ni ibamu pẹlu aṣẹ ijọba pe ki ajọ NCDC ṣayẹwo arun Korona fawọn arinrin-ajo to n wọle sorileede wa, ile ayẹwo wa l’Abuja ti fidi ẹ mulẹ pe ẹya Omicron lara arun Korona ti de Naijiria, ati pe awọn arinrinajo meji kan ti wọn de si Naijiria lati orileede South Africa ni wọn ko kinni naa wọle.
‘‘Ayẹwo naa tun fidi ẹ mulẹ pe awọn ayẹwo ẹjẹ ta a gba silẹ loṣu kẹwaa, ọdun yii, awọn kan ninu wọn ni ẹya Omicron yii ninu.”
Ajọ NCDC ni oriṣii ẹya Omicron ti ayẹwo gbe jade yii ki i ṣe eyi to maa n tete fami han lara awọn to ba lugbadi ẹ, tori naa, o lewu gidi, wọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati tọpasẹ gbogbo awọn eeyan to ni ifarakinra pẹlu awọn arinrinajo meji ọhun.
Orileede South Africa ati Botswana ni ayẹwo ti kọkọ fihan pe oriṣii ẹya Omicron lara arun Korona naa ti ṣẹ, ibẹ lo si ti n ja ranyin ju lọ bayii.
Latari iṣẹlẹ ọhun, ọpọ orileede agbaye ni wọn ti gbe gbedeke le irinajo lati awọn orileede Guusu ilẹ Afrika lọwọ yii.