Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa apapọ ilẹ wa ti ṣafihan awọn afurasi ọdaran mejilelọgbọn kan niluu Abuja ti wọn n ṣe onigbọwọ fawọn afẹmiṣofo ti wọn n ṣoro bii agbọn lagbegbe Oke-Ọya.
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja, Kọmiṣanna Frank Mba, lo ṣafihan awọn kọlọransi ẹda naa lolu ileeṣẹ ọlọpaa, lọjọ Tusidee, ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE, wọn lawọn afurasi ọdaran yii wa lara awọn to ṣakọlu sawọn arinrin-ajo rẹpẹtẹ ti wọn ji gbe lọna marosẹ Kaduna si Abuja lọsẹ to kọja lọhun-un.
Mba ni awọn kan lara awọn tọwọ ba yii ti jẹwọ pe loootọ lawọn maa n ṣeranwọ fawọn afẹmiṣofo ti wọn wa kaakiri lẹlẹgbẹjẹgbẹ ninu awọn igbo kijikiji to yi ipinlẹ Sokoto, Kaduna, Katsina ati Zamfara ka.
Lara iranlọwọ ti wọn maa n ṣe ni lati ba awọn ajinigbe ra ounjẹ, lati ba wọn ko ọta ibọn ati ibọn tuntun wọle latẹyin odi ti wọn ti lọọ ra wọn, wọn si tun maa n ba wọn ra egboogi oloro loriṣiiriṣii.
Wọn tun jẹwọ pe awọn lawọn maa n ta awọn afẹmiṣofo lolobo lati le jẹ ki wọn mọ ibi tawọn agbofinro wa, ati ọna ti wọn le tọ ti wọn o fi ni i ri wọn mu, wọn lawọn maa n tọka awọn olowo ati oloṣelu ti wọn ba fẹẹ ji gbe, ati asiko to daa lati ṣakọlu si wọn, wọn si maa n juwe awọn ileewe ti wọn ti le lọọ ji awọn akẹkọọ gbe.
Mba ni oriṣiiriṣii nnkan ija oloro lawọn ri gba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa. Lara ẹ ni ibọn AK-47 mọkandinlogun (19), ibọn atamatase GPMG kan, ibọn alayinyipo Revolver mẹta, ibọn pompo G-3 meji, ibọn SMG kan, ibọn ṣekele pistu Beretta kan, ọta ibọn ti wọn o ti i yin jẹ ọtalenirinwo din meje (453), kolo ọta ibọn mejila, ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ji gbe mẹtadinlogun (17) ni wọn gba nidii wọn.
Wọn tun ṣalaye pe mẹfa lara awọn afurasi naa lo jẹ pe mọto jijigbe lawọn yan laayo, wọn si ti jale ọhun lagbegbe Port-harcourt, Nassarawa, Abuja, Kebbi ati Zamfara, wọn a waa gba ẹnubode wa sọda si Nijee. Wọn ni Alaaji Garba lo maa n ra awọn ọkọ ole naa lọwọ wọn lorileede Niger, ṣugbọn Alaaji naa ti sa lọ bayii, wọn ṣi n wa a ni.
Bakan naa lọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan wa laarin awọn tọwọ ba ọhun, Dayyabu Mohammed lorukọ ẹ, ijọba ibilẹ Soba, nipinlẹ Kaduna, lo loun ti wa. Ibọn AK-47 marun-un (5) ni wọn ba lọwọ oun nikan, pẹlu ọta ibọn ojilerugba.
Wọn ni inu igbo Saminaka, nipinlẹ Kaduna, ni wọn ti ri i mu, o si jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe awọn ẹgbẹ afẹmiṣofo meji, ti Yẹlo ati Bidderi, loun n ba ṣiṣẹ, oun maa n ba wọn ko ọta ibọn ati nnkan ija oloro wọle lati ẹnubode ni.
O jẹwọ pe Dayyabu lo ra ọkọ ayọkẹlẹ Volkswagen Gult 3 toun fi n ṣẹsẹ rin foun, pẹlu ileri pe toun ba ti le ba wọn ko nnkan ija oloro wọle lẹẹmarun-un, ọkọ naa aa di toun patapata, ṣugbọn ẹẹkeji toun yoo ko awọn ẹru ofin naa lọwọ tẹ oun yii.
Ọwọ tun ba awọn mẹfa kan, Mohammed Lawali, Suleiman Ibrahim, Mohammed Rabo, Bashir Audu, Monsoru Abubakar ati Abubakar Hamidu, awọn ni wọn wa nidii akọlu to waye loṣu to kọja ni mọṣalaaṣi Mazakuka, nijọba ibilẹ Mashegu, nibi ti eeyan mejidinlogun ti doloogbe lojiji.
Mba ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn afurasi wọnyi, o ni wọn ti n fọwọsowọpo pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ, lati le fi pampẹ ofin gbe awọn yooku wọn, tabi ki wọn dana ya wọn.