Faith Adebọla
Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, Ọnarebu Iliasu Ọlọlade Shittu, ti fọwọ sọya pe laarin ọjọ meje pere sasiko yii, gbogbo wahala ati idunkooko-mọni awọn Fulani darandaran lagbegbe Igangan, maa dohun itan, tawọn araalu aa si le sun oorun asundọkan.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde yii, loo sọrọ naa lati fi ọkan awọn araalu balẹ latari bi awọn Fulani ṣe tun bẹrẹ akọlu sawọn agbẹ lakọtun lagbegbe naa.
O ni boun ṣe n sọrọ lọwọ yii, kọmandanti ẹṣọ Amọtẹkun fun ipinlẹ Ọyọ wa lọdọ oun, ati pe laarin wakati diẹ lawọn yoo gbe agbara wọ awọn ẹṣọ alaabo ọhun, ti wọn yoo si paṣẹ fun wọn lati tọpasẹ wọn, ki wọn si le awọn janduku Fulani to mori mu sawọn ọna oko wọn kaakiri danu.
Alaga naa fidi ẹ mulẹ fun wa pe loootọ lawọn Fulani buruku yii tun ṣakọlu sawọn agbẹ ni lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, o lawọn mẹta ni wọn yinbọn mọ bi wọn ṣe n dari bọ latọna oko wọn, bo tilẹ jẹ pe ori ko wọn yọ, wọn si wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.
Iliasu ni oun ko ti i le fidi rẹ mulẹ boya ọkan lara wọn ti wọn n pe ni Ṣeun Auditor ti ku, tori agbegbe Idere ni wọn gbe oun digbadigba lọ ni tiẹ.
O lawọn ko ṣai reti awọn akọlu yii, tori awọn mọ pe o ṣee ṣe kawọn Fulani naa fẹẹ gbẹsan bi wọn ṣe le awọn kan lara wọn niluu Igangan, nigba ti Sunday Igboho ṣabẹwo siluu naa lọsẹ to lọ lọhun-un.
Ọnarebu Iliasu tun fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni ọkunrin Fulani darandaran kan ti wọn n pe ni Wakilu wa ninu igbo agbegbe naa, o lọkunrin naa ti wa nibẹ tipẹ, tawọn eeyan si ti n mu oriṣiiriṣii ẹsun wa pe Fulani yii atawọn eeyan rẹ wa lara awọn to n ṣiṣẹẹbi lagbegbe ọhun, bo tilẹ jẹ pe oun o le fi ẹri eyi mulẹ, ṣugbọn o lo daju pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun yoo ṣiṣẹ de ọdọ rẹ nigba ti wọn ba kan lu igbo ọhun.
Alaga yii waa rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati ni suuru diẹ si i, tori owe Yoruba lo sọ pe ‘ohun ta a fẹsọ mu ki i bajẹ, ohun ta a ba fagbara mu lo n le koko’.