Ẹ gba wa o, Saraki tun ti ko tọọgi wọlu – APC Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Latari rogbodiyan to bẹ silẹ lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja, nile Saraki to wa lagbegbe GRA, Ilọrin, nibi tawọn eeyan ti fara pa lasiko adura ni iranti ọdun mẹjọ ti Oloogbe Abubakar Oluṣọla Saraki faye silẹ, ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba ni Kwara ti fẹsun kan olori ile aṣofin agba ana, Dokita Bukọla Saraki, pe oun lo ko tọọgi wọlu.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ẹgbẹ naa nipinlẹ Kwara, Alhaji Tajudeen Fọlaranmi Aro, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ni wọn ti ni lati 2019 ti Saraki ti fi ilu silẹ, ko si iṣẹlẹ ki awọn janduku kan maa da wahala silẹ, ṣugbọn dide to de bayii toun pẹlu awọn tọọgi rẹ to n ko kiri tẹlẹ lo wọlu.

Aro ni asiko ka maa lo tọọgi da ilu ru ti di afisẹyin teegun fiṣọ, fun idi eyi, APC ta ko bawọn jankudu to tẹle Saraki ṣe kọ lu awọn agbofinro.

APC ni, “Fun igba akọkọ, latigba tawọn araalu ti kọyin si Saraki atawọn ẹmẹwa rẹ, ipinlẹ wa tun ni akọsilẹ iṣẹlẹ buruku lọjọ Satide, nibi tawọn janduku ti kọ lu araalu nibi eto ti Saraki gbe kalẹ. Eleyi jẹ dida Kwara pada si asiko ti wọn n lo tọọgi lati ṣejọba, ati fifi owo ilu sanwo oṣu fawọn ọdaran”.

Ẹgbẹ ọhun ni bo tilẹ jẹ pe awọn ki Saraki kaabọ lati ibi to sa lọ tabi to lọọ fara pamọ si lẹyin tawọn foju ẹ gbọlẹ, ṣugbọn awọn bẹ ẹ lati ma tu awọn janduku tijọba to wa lori aleefa ti tẹ ri pada sigboro.

Ṣugbọn o, iwadii wa fi han pe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to da awọn eeyan laamu lawọn sọja mu balẹ nitosi ibi ti eto adura fun Baba Saraki ti n lọ lọwọ, ki i ṣe awọn tọọgi lo da ilu ru bawọn kan ṣe n gbe e kiri.

Lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣalaye pe nigba ti afurasi naa n yinbọn lati fi halẹ mọ awọn eeyan lawọn sọja to wa nibẹ gbana oju ẹ.

Fun idi eyi, ohun to ṣẹlẹ naa ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu wiwọlu Saraki tabi eto adura to waa ṣe fun baba rẹ.

Leave a Reply