Ẹ gbagbe nipa pinpin Naijiria, ẹ ja fun iṣọkan wa-Ọbasanjọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, tun ti ran awọn ti wọn n ja fun idasilẹ Orilẹ-ede Yoruba leti lẹẹkan si i pe ki wọn gbagbe nipa pinpin Naijiria, niṣe ni ki wọn ṣiṣẹ fun iṣọkan orilẹ-ede yii ati ilọsiwaju rẹ.

Ilu Abẹokuta ni Ọbasanjọ ti sọrọ yii ninu ọgba rẹ ti i ṣe OOPL, l’Ọjọruu, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹfa yii. Agba oṣelu naa sọ pe loootọ ni Naijiria asiko yii ko fara rọ, ṣugbọn pinpin kọ ni ojutuu si iṣoro to n koju rẹ.

“Ko si ọmọ Naijiria rere ti ọkan rẹ yoo balẹ si ohun to n ṣẹlẹ lọwọ lasiko yii, ti ko si aabo kankan, to jẹ ko pin, ko pin, lohun ta a ṣaa n gbọ. Ṣugbọn emi gbagbọ ninu Naijiria to wa papọ, ti gbogbo wa yoo ti ni ẹtọ sohun to tọ si wa, ti ẹni kan ko ni i ṣe ẹru ẹni keji.

“Ba a ṣe jẹ oriṣiiriṣii ẹya yii n fun wa lagbara pẹlu ba a ṣe wa papọ. To ba jẹ Ilẹ Olominira Oduduwa nikan la ni bawọn to n beere ẹ ṣe fẹ, awọn eeyan ibẹ yoo kere si Naijiria to jẹ odidi.

“Lasiko yii to jẹ iṣọkan ilẹ Afrika kaakiri lawọn eeyan dudu n ṣiṣẹ le lori, njẹ o waa ba laakaye mu ko jẹ bi awa yoo ṣe pin orilẹ-ede tiwa la n sọ.

“ Bi ilẹ Hausa ba da duro, ti ilẹ Ibo da duro, ti Yoruba naa da duro, awọn ẹya ti ko to nnkan bii Jukun nkọ?  Awọn Gbasama nkọ pẹlu awọn ẹya keekeeke mi-in? Bawo ni tiwọn yoo ṣe ri? Kin ni yoo ṣẹlẹ si wọn? Ohun ti awọn wọnyi le fi da nnkan kan ṣe ko ju pe wọn jẹ ọmọ Naijiria lọ, ṣe a n ronu nipa tiwọn ṣa ka too maa sọrọ idasilẹ ilẹ olominira kaluku? Abi ti ara wa nikan la n ro?

“O ti ṣẹlẹ ri, a ti ri i ri. Wọn pin India si meji, o di India ati Pakistan, titi doni ni wọn ṣi n ba ara wọn ja. Wọn pin Yugoslavia si oriṣiiriṣii orilẹ-ede, wọn ko ti i ri i yanju titi doni. Wọn pin Sudan si meji, wọn yọ Guusu Sudan jade nibẹ, mi o nigbagbọ pe eyi mu daadaa kan ba Sudan loni.

“Emi nigbagbọ pe yoo dẹrun lati ṣiṣẹ pọ fun atunṣe ilu wa ta a ba wa papọ, ju ka pin ara wa lọ. Ọpọlọpọ nnkan lo ti bajẹ loootọ, ṣugbọn awọn nnkan yii ṣee tunṣe ta a ba wa papọ ju ka tuka, ka waa maa ba ara wa ja, ka maa nawo wa sidii pe a fẹẹ ra nnkan ogun ta oo maa fi ba ara wa ja lọ. Ẹ jẹ ka ronu si i’’

Bẹẹ l’Ọbasanjọ wi.

 

Leave a Reply