Faith Adebọla
Lai ka bi awuyewuye ṣe gbode kan lori iyansipo aarẹ ati igbakeji rẹ ti wọn jẹ ẹlẹsin kan naa lasiko yii, gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Amofin agba Babajide Faṣọla, ti ni ọgẹdẹ lasan ni ọrọ ẹsin, ko to nnkan ti a n lọ adaa bẹ, o loun nigbagbọ pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lawọn eeyan ṣi maa dibo fun lọdun 2023, latari awọn aṣeyọri ribiribi tawọn ti ṣe.
Bakan naa lo sọ pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu loun gbagbọ pe o le tukọ iṣakoso orileede yii debute ayọ ti gbogbo araalu fẹ.
Faṣọla sọrọ yii nigba to n dahun ibeere lori eto tẹlifiṣan Channels lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. O loun ni toun ko fara mọ siso ọrọ ẹsin papọ mọ eto iṣejọba, o ni ọrọ ara-ẹni lọrọ ẹsin, inu ile ẹni si la ti i jẹ ekute onidodo lo yẹ ko jẹ, yara kaluku lo yẹ ki ijiroro ẹsin ti maa waye.
“Ero mi lori ọrọ ẹsin ko mun rara, mo ti sọ ọ lọpọ igba, emi ro pe ọrọ ẹsin ki i ṣe ohun ta a maa maa gba bii ẹni gba igba ọti, ọrọ abẹle ni, inu ile kaluku ati ileejọsin lo yẹ ka ti maa sọ ọ.
“Ẹsin rẹpẹtẹ lo wa teeyan le ṣe, ko si sijọba to ka ẹsin pato si dandan, tori ọrọ ara-ẹni ni. Gbogbo adura itagbangba ti a n gba wọnyi, emi ro pe o yẹ ka jawọ ninu ẹ, ka lọ sori koko ọrọ gidi. Ẹnikẹni to ba wa lori ipo ti wọn yan an si, ki tọhun gbaju mọ iṣẹ rẹ ni.
“Mo ro pe nigba mi-in, ko yẹ ki aya maa ja wa. To ba jẹ loootọ ni ọrọ ẹsin laarin aarẹ ati igbakeji ẹ wuwo to bawọn eeyan ṣe n sọ ọ yii, ibo ọdun 2023 lo maa fi han bẹẹ, ibi temi si duro si niyẹn.
Lajori ohun tawọn eeyan fẹ ni ipese omi ẹrọ, ileewe, eto ilera to jiire ati awọn nnkan amayedẹrun. Ta a ba wo o daadaa, igbakeji aarẹ ẹlẹsin Kirisitẹni ati aarẹ ẹlẹsin Musulumi ti wa to jẹ pe bi wọn ṣe n pa awọn eeyan ni ṣọọṣi, ti wọn n pa awọn aṣaaju ẹsin, bẹẹ ni wọn n pa wọn ninu mọṣalaaṣi. Ki la waa n sọ gan-an?
Ohun to yẹ ko jẹ awọn oludije funpo aarẹ logun ni bi wọn ṣe maa wa ojuutu si iṣoro araalu ni Naijiria. Awuyewuye ta a fẹẹ gbọ niyẹn. Bawo la ṣe fẹẹ tukọ orileede yii lọ sebute aṣeyọri to wa niwaju, ta lẹni to dara ju lọ lati wakọ naa debute ogo?
Lero temi o, Aṣiwaju Bọla Tinubu lẹni to kaju ẹ ju lọ, tori mo ti ba a ṣiṣẹ, mo si mọ ohun to le ṣe ati agbara ẹ. Asiko ree lati yẹ ikunju oṣuwọn kaluku wọn wo.
Lori ipilẹ ohun ta a ti ṣe, awọn eeyan le gbe iṣakoso kin-in-ni ati ikeji yẹ wo, ki awọn oludije yii sọ oju abẹ nikoo fun wa. Ta a ba ro o daadaa, ti a tun un ro, awọn ọmọ Naijiria to ba ṣe laakaye maa dibo fun ẹgbẹ APC, tori asiko to le koko bii oju ẹja la ṣiṣẹ sin orileede yii. Ko sijọba to koju arun Korona bi a ṣe ṣe, ko sijọba to koju ọda owo ati awọn nnkan amuṣọrọ latari ogun to n lọ lagbaaye bii tiwa, bo tilẹ jẹ pe awa kọ la n ja ogun, sibẹ, a fi ọgbọn tukọ ọrọ-aje orileede yii lọna rere lati fun awọn araalu ni ireti ati idunnu. Mo woye pe a maa jawe olubori lọdun 2023.” Bẹẹ ni Faṣọla sọ.