Pẹlu ibinu ni Aarẹ Ọna-kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams, fi sọrọ si Gomina ipinlẹ Zamfara, Muhammed Matawalle, o ni ẹni ba moju gomina naa ko kilọ fun un pẹlu irọ buruku to n pa kiri pe awọn eeyan apa Guusu ilẹ wa n pa awọn ara Ariwa, iyẹn awọn ara Oke-Ọya, ati pe wọn gbọdọ dawọ eleyii duro ti wọn ko ba fẹ ki awọn Hausa naa gbẹsan iwa yii lara awọn eeyan wọn to wa nilẹ Hausa.
Gani ni afi ki wọn tete kilọ fun ọkunrin naa gidigidi, ko ma fi ọrọ ẹlẹyamẹya ṣe oṣelu to le da wahala silẹ.
Gani Adams ni afi ẹni ti yoo ba purọ lo ku, lo maa sọ pe awọn ẹya Guusu kọju ija si awọn eeyan Oke-Ọya. O ni gbogbo awọn ara Oke-Ọya to wa ni ilẹ Yoruba ni wọn n ṣiṣẹ aje wọn nibi ti ko sẹni to di wọn lọwọ. Aarẹ ni ko si ẹni to le di ẹnikẹni to ba n ṣiṣẹ rẹ lọna to tọ lọwọ, afi awọn ti wọn ba jẹ arufin nikan ni ilẹ Yoruba ko ni i faaye gba.
O ni oun ko mọ ibi ti Matawalle ti ri iroyin to n gbe kiri, nitori gbogbo awọn ti wọn jẹ atọhunrinwa ti wọn huwa ọdaran paapaa, ko sẹni to fọwọ kan wọn, awọn agbofinro ni wọn fa wọn le lọwọ.
Ọkunrin naa ni ‘Mo n sọrọ lorukọ gbogbo ọmọ Yoruba pe ko sẹnikẹni to di awọn eeyan Oke-Ọya lọwọ. A ko di awọn ti wọn n ṣiṣẹ aje wọn lọna ẹtọ lọwọ, oju si gba mi ti pe odidi gomina le ma sọ iru ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ yii kaakiri.’
O waa rọ ọ lati yee lo ọrọ ẹlẹyamẹya lati fi maa wa ojurere ẹgbẹ oṣelu APC to n gbero lati darapọ mọ bayii. O ni ki Matawalle rọra kọja sinu ẹgbẹ APC to n lọ lai da wahala kankan silẹ, ki wọn le baa maa fi ojurere wo o, ki wọn si le fun un ni anfaani lati tun dupo lọdun 2023.
Bakan naa ni Aarẹ Adams koro oju si ọrọ kan ti Minisita fun ọrọ abẹle nile wa tẹlẹ, Abdurahman Dambazzau, sọ pe ko si iyatọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua OPC, ati ẹgbẹ awọn ọmọ Ibo IPOB, pẹlu Boko Haram.
Aarẹ ni bo tilẹ jẹ pe agbẹnusọ ẹgbẹ OPC ti fun ọkunrin yii lesi ọrọ rẹ, sibẹ, o yẹ ki awọn agbaagba ilẹ Hausa maa ko awọn eeyan naa ni ijanu ki wọn yee maa sọsọkusọ kiri.
Bakan naa ni ẹgbẹ agba Yoruba, YCE ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti gomina ipinlẹ Zamfara sọ yii, wọn ni ọrọ ti ko mu ọgbọn dani, ti ko nitumọ, ti ọkunrin naa ko si ni ẹri kan lati fi gbe e lẹsẹ lo n sọ kiri. Ẹgbẹ naa ni ọrọ to le da ogun silẹ ni gomina naa n sọ.