Ọlajide Alabi
Ọjọ meje pere ni Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, fun awọn araalu to bani ibọn ati ọta rẹ lati fi da a pada si ọdọ ọga awọn Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, lo sọrọ naa niluu Akurẹ ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin rẹ, Donald Ojogo, fọwọ si.
Ojogo ni Akeredolu ti pasẹ pe ileeṣẹ awọn Amọtẹkun to wa ni Pa Fasoranti Garden, niluu Akurẹ, ni ki wọn maa ko ibọn ati ọta naa lọ.
O waa rọ awọn to ba ni awọn ohun ija yii lọwọ lati lo anfaani ọjọ meje tijọba fun wọn yii lati ko o silẹ. O ni awọn eleto aabo yoo bẹrẹ si i gbe igbesẹ to yẹ lori wọn lẹyin ti ọjọ meje naa ba pe.
Akeredolu fi kun un pe awọn ti ko ba le lọọ ko ibọn naa silẹ funra wọn fun idi kan tabi omi-in le pe nọmba yii 08079999989, nibi ti wọn yoo ti sọ igbesẹ to yẹ ki tọhun gbe fun un.