Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Gẹgẹ bi wọn ṣe kede pe aawẹ awọn Musulumi, iyẹn Ramandan, yoo bẹrẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti rọ gbogbo Musulumi lati lo akoko oṣu Ramandan naa lati gbadura fun ipinlẹ naa ati orile-ede Naijiria lapapọ.
Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye, fi sita lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti sọ pe Gomina Abdulrazak ki gbogbo Musulumi jake-jado agbaye ku oriire ati amojuba oṣu tuntun, iyẹn Ramadan. O tẹsiwaju pe Gomina rọ gbogbo Musulumi lati lo anfaani naa fi sunmọ Ọlọrun Ọba Allah, ki wọn si tọrọ aforiji ẹṣẹ, ki wọn gbadura kikan kikan fun ipinlẹ Kwara ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ. Bakan naa ni gomina ki Ẹmaya tiluu Ilọrin, Dokita Ibrahim Sulu-Gambari, ati olugbe Kwara lapapọ ti oṣu ọhun soju ẹmi wọn.