Gbenga Amos, Ogun
“Ẹ jẹ ki n lo anfaani yii lati sọ fawọn eeyan wa pe oṣelu ati akitiyan rẹ ti bẹrẹ bayii, a gbọdọ kọyin si iwa ẹtanu, ọtẹ ati aawọ nidii oṣelu. Bi orileede wa ṣe maa goke agba daadaa lo gbọdọ mumu laya wa, ati ninu iwa wa.
“A o gbọdọ jẹ ki oṣelu ba nnkan tawa eeyan ipinlẹ Ogun n gbadun jẹ. Ijọba yii ti ṣe gbogbo nnkan to le ṣe lati din ariwo gee lagbo oṣelu ku, bẹẹ la ti mu adinku ba iwa ọdaran, irufin ati tawọn janduku ku, kawọn eeyan wa le maa lọ sidii ọrọ-aje wọn pẹlu ifọkanbalẹ.”
Lara awọn ọrọ iparọwa ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ṣe niyi lasiko ayẹyẹ ifilọlẹ awọn oloye ẹgbẹ ọmọ Oke-Ọya, ti wọn pe ni Arewa Consultative Forum, ACF, ẹka ti Guusu/Iwọ-Oorun, eyi to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an, ni gbọngan aṣa nla ti June 12 Cultural Centre, to wa ni Kutọ, l’Abẹokuta, olu-ilu ipinlẹ Ogun.
Nibi ayẹyẹ naa ni wọn ti tun fi oye ati awọọdu Aṣoju Alaafia (Ambassador of Peace) da gomina naa lọla.
Alaga apapọ fun ẹgbẹ ACF, Oloye Audu Ogbe, ẹni ti Alaaji Munir Mohammed ṣoju fun, ṣe sadankata fun Dapọ latari bo ṣe jẹ ki alaafia jọba laarin awọn eeyan Oke-Ọya to wa nipinlẹ naa atawọn oniluu, ti kaluku wọn si n lọ sẹnu okoowo ẹ lai si wahala kankan.
O ni ko sibi ti wọn ko ti mọ ipinlẹ Ogun si ibi ti awọn eeyan rẹ ti ko ni mọra, ti wọn si n huwa bii ọrẹ sẹni gbogbo. Lẹyin eyi lo parọwa si gomina naa pe ko bẹ awọn eeyan ilẹ Yoruba lati ma ṣe dẹyẹ sawọn Hausa/Fulani to wa laarin wọn, kaka bẹẹ, niṣe ni ki wọn ṣewadii iwa ọdaran to ba waye, ki wọn si fiya jẹ ẹni to ba jẹbi iwakiwa lai ṣojusaaju.
Dapọ Abiọdun kadii ọrọ tiẹ pẹlu idupẹ fun awọọdu ti wọn fun un, o si fi da wọn loju pe ayọ ati igbaye-gbadun araalu ni ijọba oun yoo tubọ tẹpẹlẹ mọ, lai fi ti ẹya tabi ede ẹnikẹni ṣe.