Adewale Adeoye
Bo ṣe ku diẹ ki iṣakoso ijọba Muhammadu Buhari pari, Aarẹ orileede yii ti sọ pe kawọn ọmọ orileede yii ma mikan rara, nitori pe oun yoo gbe iṣakoso ijọba orileede yii le ẹni to kunju oṣunwọn daadaa, ti yoo si gbe ogo orileede yii de ebute ayọ lọwọ.
Aarẹ Buhari sọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lakooko to n ṣi ileeṣẹ ifọpo kan ti oniṣowo pataki nni, Aliko Dangote, kọ siluu Ibẹju Lekki, nipinlẹ Eko.
Buhari ni gbogbo ohun ti ijọba oun ko le ṣe, tabi ti ko le pari nijọba Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu yoo pari patapata, ti ọrọ aje orileede yii aa si burẹkẹ si i daadaa.
Atẹjade pataki kan, eyi ti Ọgbẹni Femi Adeṣina to jẹ agbenusọ Aarẹ Buhari fọwọ si lo ti ṣapejuwe ileeṣẹ ifọpo ti Dangote kọ gẹgẹ bii eyi ti yoo ṣeranlọwọ gidi fun ọrọ aje orileede wa.
Aarẹ ni, ‘ Inu mi dun gidi pe ẹni to kunju oṣuwọn daadaa, iyẹn Tinubu, ni mo fẹẹ gbe iṣakoso ijọba orileede yii le lọwọ bayii, mo mọ daadaa pe yoo ṣatunṣe sọrọ aje ilẹ wa lọna tawọn oniṣowo ilẹ okeere paapaa yoo fi waa da ileeṣẹ silẹ nibi, ti gbogbo nnkan yoo si maa lọ deede fawọn ọmọ Naijiria.
O ni, ‘Ileeṣẹ ifọpo nla ta a n ṣi loni-in-ni yii jẹ akọkọ iru ẹ nilẹ wa, ati nilẹ Adulawọ. Apẹẹrẹ pe bi ijọba ba faaye gba awọn oniṣowo kọọkan, wọn le ṣohun to daa saarin ilu niyi. Ijọba gbọdọ faaye gba awọn oniṣowo, ki awọn alaṣẹ ijọba si tun ṣofin ti yoo mu nnkan dẹrun fawọn araalu lo maa ran awọn eeyan lọwọ gẹgẹ bi oniṣowo Dangote ti ṣe kọ ileeṣẹ ifọpo tuntun siluu Ibẹju Lekki bayii”.
Lara awọn olori orileede ti wọn wa nibi ṣiṣi ileeṣẹ ifọpo ti Dangote kọ siluu Ibẹju Lekki, nipinlẹ Eko ni: olori orileede Togo, Niger, Senegal ati aṣoju orileede Chad.