Loootọ ni wọn ba foonu iya to ku lọwọ mi, ṣugbọn emi kọ ni mo pa a-Sunday

Oluṣẹyẹ Iyiade,

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti ṣafihan  Mima Chinecherem, ìyẹn ọmọkunrin ọmọọdun mẹtadinlọgbọn kan tọwọ tẹ lori iku iya agbalagba ẹni ọgọrin ọdun kan, Abilekọ Aderibigbe Felicia, niluu Kọstain, nijọba ibilẹ Odigbo.

Mima, ẹni tọpọ eeyan mọ si Sunday Akọpẹ ni wọn fẹsun kan pe o lọọ ka iya arugbo ọhun mọ’nu oko rẹ l’Ọjọruu, Wẹside, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, nibi to ti fipa ba a lo pọ titi to fi ku.

Nigba to n ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an fun akọroyin ALAROYE lasiko tawọn ọlọpaa ṣafihan rẹ, Mima ni lati ọdun 2016, iyẹn ni nnkan bii ọdun meje sẹyin loun ti mọ Oloogbe Aderibigbe.

O ni o wa lara awọn ti oun n ba ṣiṣẹ ọpẹ kikọ lagbegbe Kọstain, ati pe inu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, loun ti foju kan mama naa gbẹyin.

O ni loootọ ni wọn ba foonu oloogbe ọhun lọwọ oun lalẹ ọjọ ti oun fẹẹ waa ta mariwo ọpẹ mọ ile rẹ, ṣugbọn oun kọ loun pa a. O fi kun un pe inu oko loun ti ri foonu naa, ati pe niṣe loun fẹẹ mu un lọọ fi han awọn ọmọ oloogbe yii ati ada ti oun ri nibi aala oko ọhun ni wọn fi ri oun.

Afurasi ọdaran to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi, ọhun ni inu oko loun ti rí foonu naa, ti oun si mu un.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ti ni ọkunrin naa ko ni i pẹ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.

 

Leave a Reply