Wọn ti wọ baba onile to lodi sofin eto ikọle lọ siwaju adajọ

Ismail Adeẹyọ

Baba onile kan, Kenneth Okenini, ni wọn ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti Ikẹja, niluu Eko, lori ẹsun pe o lodi sofin eto ikọle nipinlẹ Eko.

Kenneth ni wọn lo ni ile alaja mẹta kan to da wo lulẹ lagbegbe Adesẹgun Okunuga, ni Ikate-Elegushi, ijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko.

Ọkunrin yii ni wọn fẹsun oriṣiriṣii kan, ninu ẹ ni pe o kọ eti ikun sofin eto ikọle ti ipinlẹ Eko, eyi tajọ to n ri sọrọ ile kikọ nipinlẹ naa gbe kalẹ ni ibamu pẹlu ofin ati ilana aatẹle.

Ẹsun mi-in ti wọn tun fi kan an ni pe ki ile naa too da wo lawọn ajọ ọhun ti kilọ fun un pe ile to n kọ ọhun ko lẹsẹ nilẹ to, bẹẹ si ni ko ba ofin ile kikọ ipinlẹ yii mu.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe o mọ-ọn-mọ fẹẹ da ẹmi awọn eeyan legbodo latari bo ṣe ta ko ilana ti awọn ajọ to n ri si idagbasoke ilu ati eto ikọle ipinlẹ Eko gbe kalẹ.

ALAROYE gbọ pe ile alaja mẹta ọhun da wo lulẹ lọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii. Ti ajọ to n ri sọrọ ile kikọ ti ile naa pa lọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti wọn ṣayẹwọ sibẹ, ti wọn si ṣakiyesi pe gbogbo ohun eelo ti wọn fi kọle naa ni ki i ṣe ojulowo.

Ṣugbọn niṣe ni Kenneth ja gbogbo nnkan ti wọn lẹ mọ ara ile yii gẹgẹ bii ikilọ danu, to si n ba iṣẹ tirẹ lọ, ko too di pe ile naa pada wo danu.

Bakan naa ni wọn tun ni iwadii fi han pe onile yii ko ṣe iwe kankan lori ilẹ ọhun ki wọn too bẹrẹ iṣẹ lori rẹ, leyii ti wọn lo lodi sofin eto ikọle ti ipinlẹ Eko, eyi ti wọn ni ijiya nla wa fun iru iwa ọdaran bẹẹ labẹ ofin ipinlẹ Eko ti ọdun 2015 ati 2019.

Nigba ti adajọ bi Kenneth boya o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi, ọkunrin yii loun ko jẹbi ẹsun ọhun.

Lẹyin eyi ni ile-ẹjọ fun un lanfaani beeli, ti wọn si ni ko lọọ san ẹgbẹrun-un lọna ẹdẹgbẹta Naira, pẹlu oniduuro meji ti wọn ni iwe ti wọn fi n sanwo ori, leyii to gbọdọ ba orukọ wọn mu.

O waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun yii.

 

Leave a Reply