Awọn agbebọn ṣoro ni Kwara, wọn paayan, wọn ji owo ati foonu gbe lọ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Afaimọ lọrọ eto aabo to dẹnu kọlẹ ni Kwara, ko ti doriṣa akunlẹbọ sijọba lọrun bayii, pẹlu bi awọn agbebọn ṣe n ṣakọlu sawọn araalu lati ọsẹ to kọja.  Ni báyìí, awọn ẹni ibi naa tun ya bo abule meji nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ naa, wọn pa ẹni kan, wọn tun gba foonu atowo lọ.

ALAROYE gbọ pe lọsẹ to kọja yii ni awọn agbebọn naa yabo abule Gure,  ti wọn bẹrẹ si i rọjo ibọn, ti onikaluku si bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi ara wọn. Ọdọmọbìnrin kan fara gbọta, to si ku loju-ẹsẹ. Bi awọn oṣika ẹda naa ṣe ri ohun to ṣẹlẹ ni wọn na papa bora.

L’ọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un yii, ni awọn agbebọn kan tun ya bo abule Boriya, nijọba ibilẹ Baruten yii kan naa, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to fara pa, sugbọn lẹyin ti wọn fi ọta ibọn dara soju afẹfẹ tan ni wọn gba owo ati ọpọlọpọ foonu lọ lọwọ awọn eeyan ọhun, ti gbogbo awọn olugbe abule kereje-kereje nijọba ibilẹ Baruten, si ti wa ninu hila-hilo bayii.

Awọn agbaagba lẹkun Ariwa Kwara, (Kwara North) ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii. Abẹnugan nile-aṣofin ipinlẹ naa,Yakubu Danladi-Salihu, bú ẹnu atẹ Lu iṣẹlẹ naa ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii. O ni ijọba yoo wa gbogbo ọna lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu. Bakan naa lo rọ gbogbo araalu ki wọn wa loju ni alakan fi n ṣọri, ẹni ti wọn ba ri to n rinrin aitọ tabi fura si, ki wọn fi to awọn ẹṣọ alaabo leti.

O tẹsiwaju pe oun mọ ipalara ati ibanujẹ nla ti akọlu yii ti mu ba ọpọ mọlẹbi, sugbọn ijọba yoo gbe igbesẹ to tọ, ọwọ yoo sí tẹ awọn amookunṣika ẹda naa, ti wọn yoo si foju wina ofin ijọba. O ni awọn o ni i sun, bẹẹ lawọn ko ni sinmi lati ri i daju pe aabo to peye wa fun gbogbo araalu  lapapọ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Ọkasanmi Ajayi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni awọn adigunjale lo kọ lu onisatakisi kan niluu Boriya, ti wọn si gba owo, ti wọn tun ji ọpọ foonu gbe lọ.

Leave a Reply