Lẹyin ti Salaudeen pari ija fun tọkọ-tiyawo tan to n lọ sile lo ku sinu koto to ja si

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un yii, ni iṣẹlẹ kayeefi kan ṣẹlẹ lagbegbe Irewọlede, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti ri oku ọkunrin kan, Salaudeen, ti ọpọ eniyan mọ si “Bọlakalẹ” Wọn ni nigba to n dari bọ lati ibi to ti lọọ pari ija laarin tọkọ-taya kan bọ lo ti ja si koto pẹlu ọkada rẹ, oku ẹ ni wọn gbe jade ninu koto ohun.

ALAROYE gbọ pe oloogbe yii, to jẹ ọmọ agboole Òwánláàrógò, lopopona Niger, niluu Ilọrin, gbera nile rẹ ati lọọ pari ija fun ọrẹ rẹ ati iyawo rẹ ti wọn ni gbolohun asọ laarin ara wọn lọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un yii. Won ni o ti ba won pari aawọ naa, ṣugbọn nigba to n dari pada bọ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ lo ja si koto pẹlu ọkada rẹ ni Opopona Irewọlede, latari oju ọna ti wọn n tunṣe lọwọ.

Wọn ni Salaudeen pe iyawo rẹ nile, o si salaye  fun un pe oun fẹ lọọ pari ija laarin ọrẹ oun ati iyawo rẹ, o si see ṣe ki oun pẹẹ wale. Lasiko naa lawọn ọmọ oloogbe yii ni ki baba naa maa ba wọn rẹ burẹdi bọ to ba n bọ wale, lai mọ pe ọrọ aṣọ mọ wọn niyẹn. Iyawo ni oun pe foonu ọkọ oun pada titi, ṣugbọn ko gbe foonu naa lojo Tọsidee yii.  O ni laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni ẹni kan gbe foonu rẹ, ti wọn si ni ọkọ oun ti dagbere faye.

Alaga ajọ to n tun ọna ṣe ni Kwara (Kwara State Road Maintenance Agency) KWARMA, Akeem Adegboye, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni eeyan kan lo ku nibi iṣẹlẹ naa, ati pe o ya oun lẹnu bo se ko sinu koto ọhun tori pe wọn ti gbe nnkan sibi koto naa nitori awọn ọkọ tabi ọkada to ba fẹẹ kọja.

 

Leave a Reply