Faith Adebọla
Alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Sẹnetọ Iyorchia Ayu, ti ṣekilọ fawọn ọmọ Naijiria lati ma ṣe reti pe nnkan le ṣenuure labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari, o ni nnkan maa le koko si i ni, imọran kan ṣoṣo toun si le gba wọn ni ki kaluku lọọ mura lati le ijọba naa danu, o nijọba Eṣu ni.
Ayu sọrọ yii ninu iṣẹ ikini ku ọdun tuntun, eyi to wa ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ ki-in-ni, oṣu ki-in-ni, ọdun yii, lolu-ile ẹgbẹ PDP, l’Abuja.
O ni iroyin ayọ kan ṣoṣo toun ni fawọn eeyan ni pe ki wọn nireti, tori o da oun loju pe ijọba naa maa too kogba sile, igba ọtun si maa de, eyi ti yoo tu araalu lara, gẹgẹ bo ṣe wi.
“Ko si nnkan rere kan to tun le ṣẹlẹ lasiko iṣakoso to wa lode yii, niṣe ni wọn ṣi maa mule aye lekoko fun yin, niṣe nijọba yii n ge iwalaaye awọn araalu ku.
“Ireti nikan lo ku tawọn ọmọ orileede yii fi n gbe aye wọn, gbogbo eeyan lọrọ ijọba yii ti su, ojumọ kan, iroyin aburu kan ni. Ka sootọ, ireti lo mu kawọn eeyan ṣi maa rọju bọ lati bii ọdun mẹfa sẹyin, to jẹ niṣe ni nnkan nira koko bii oju ẹja.
“Mo rọ ẹyin ọmọ Naijiria lati lọọ gbaradi lati juwe ọna ile fun ijọba yii, niṣe ni kẹẹ le wọn danu. O daju pe ẹgbẹ apọniloju ti wọn n pe ni APC yii maa dopin. Ẹ jade lọọ forukọ silẹ, kẹ ẹ si gba kaadi idibo yin, ẹ ba ara yin sọrọ, ẹ ko ara yin jọ, kẹẹ le eṣu yii danu tefetefe.
“Idi ti ọdun 2022 fi ṣe pataki fun gbogbo wa niyẹn, tori ireti wa ni lati bọ lọwọ inira yii laipẹ.”
Ayu lo sọrọ bẹẹ.