Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣekilọ pe ki awọn eeyan ma waa ki oun nile lọjọ ọdun Ileya yii o. Arun koronafairọọsi to wa nita yii lo fa a, Aarẹ ni oun ko fẹ ki kinni naa maa ran kiri si i lati ọdọ oun. O ni ki kaluklu ṣe ọdun nile rẹ, nitori ohun ti oun paapaa yoo ṣe niyẹn.
Ṣe ni gbogbo ọjọ ọdun bayii ni awọn agbaagba ilu, awọn oloṣelu nla-nla, awọn oṣiṣe ijọba pataki ati awọn aṣaaju ẹsin maa n lọ si ọdọ Aarẹ lati ki i ku ọdun, ti wọn yoo si ba a ṣere. Ṣugbọn Buhari ni iyẹn ko ni ṣee ṣe lọdun yii, nitori laarin awon ẹbi oun, ninu ile oun, loun yoo ti ṣe ọdun, oun ati awọn nikan naa si ni.
Alaye ti agbẹnusọ fun Aarẹ, Garba Shehu, gbe jade fi kun un pe Buhari kilọ pe ki awọn eeyan ma kojọ pọ lati kirun yidi ọdun, afi ti wọn ba ti ṣeto lati jinna sira wọn nibẹ, ti gbogbo wọn si gbọdọ lo ibomu wọn. O ni ohun ti awọn olori ẹlẹsin Islaamu ni Naijiria fọwọ si niyi, gbogbo eeyan lo si gbọdọ tẹ le e.