Wọn dana sun awọn adigunjale ti wọn fọ banki l’Okeho, ti wọn tun pa ọlọpaa kan

Nnkan ko ṣenuure fun aọn adigunjale kan ti awọn araalu dana sun ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lẹyin ti wọn pa ọlọpaa kan ati ọmọkunrin kan niluu Okeho, nijọba ibilẹ Kajọla, nipinlẹ Ọyọ.

ALAROYE gbọ pe ni irọlẹ ọjọ naa lawọn adigunjale naa ti wọn to bii meje ya wọ ilu ọhun, ti wọn si mori le agọ ọlọpaa to wa nibẹ, nibi ti wọn ti kọkọ doju ija kọ awọn agbofinro naa, ti wọn si da wọn riboribo.

Bi wọn ṣe kuro ni agọ ọlọpaa yii ni wọn gba First bank to wa niluu naa lọ lati lọọ ja wọn lole nibẹ. Wọn yinbọn pa ọlọpaa to n ṣọ banki naa, ibọn si tun ba ọmọkunrin kan to jade lati woran nigba ti iṣẹlẹ naa n lọ lọwọ. Oju ẹsẹ niyẹn naa si jade laye.

Ni kete ti awọn ọdẹ ilu gbọ nipa awọn adigunjale ọhun ni wọn pin ara wọn kaakiri awọn ọna to wọ ilu yii. Lẹyin eyi ni awọn ọdẹ yii atawọn adigunjale naa bẹrẹ si i dana ibọn funra wọn. Oju ẹsẹ lawọn ọdẹ yii ti pa mẹrin ninu wọn. Awọn ọdẹ ilu Ilero lo mu awọn mẹta yooku nigba ti wọn n gbiyanju lati gba ọna ilu naa sa jade.

A gbọ pe niṣe ni awọn adigunjale naa fọn owo soke lati fi tan awọn araalu ki wọn le baa raaye sa lọ, ṣugbọn eyi ko jẹ awọn eeyan rara.

Niṣe ni wọn dana sun awọn adigunjale tọwọ tẹ naa bii ẹran ogunfe.

Leave a Reply