Faith Adebọla, Eko
Yoruba bọ, wọn ni ogun awitẹlẹ ki i pa arọ, arọ to ba gbọn, ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si oju-ọjọ ati ọrọ omi (Nigeria Hydrological Services Agency) NIHSA, ti kede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe kawọn gomina ati araalu tete bẹrẹ si i gbaradi lati dena omiyale ati akunya omi, tori ejiwọwọ ojo maa balẹ lọdun ta a wa yii.
Ọga agba ajọ naa, Ọgbẹni Clement Nze, lo kede ọrọ yii niluu Abuja nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, o ni ta o ba ṣọra, afaimọ ki ojo arọọda ma ṣediwọ fawọn iṣẹ ode ti wọn n ṣe lọwọ, tori ẹ loun ṣe n gba awọn gomina atawọn kọngila nimọran lati tete jaramọ iṣẹ eyikeyii to ba jẹ mọ titi ṣiṣe, kọta gbigbẹ ati lila, atawọn iṣẹ mi-in ti ki i ṣe iṣẹ abẹle.
Clement ni lati bii ọdun mẹsan-an sẹyin ni awọn orileede to wa lagbegbe Niger Basin, eyi ti Naijiria jẹ ọkan lara wọn, ti n koju omiyale ati ojo ojoojumọ, bọdun si ṣe n gori ọdun ni kinni naa n legba kan si i.
O ni iṣẹ iwadii ati imọ ijinlẹ ti fihan pe ojo ti ọdun 2021 yii maa pọ gidi, ati pe awọn daamu (dams) ti wọn fi n dari omi maa kun akunfaya, eyi si le jẹ kawọn odo ọsa ati okun gbalejo omi rẹpẹtẹ.
O fi kun un pe awọn onimọ ijinlẹ si n baṣẹ lọ lẹnu iwadii wọn, lati le sọ pato awọn ipinlẹ ati agbegbe ti ọrọ naa maa kan gbọngbọn ju lọ laipẹ.
Lara awọn igbesẹ tọkunrin naa damọran fawọn gomina ati ijọba apapọ lati gbe ni pe ki wọn kegbajare ọrọ yii fawọn araalu, ki wọn si da wọn lẹkọọ nipa igbesẹ to yẹ ki idile kọọkan gbe.
O tun rọ ijọba lati tete bẹrẹ si i la awọn gọta ati kanaali, ko ma si idiwọ fun ọgbara lati ṣan geere, ki wọn si maa ko awọn idọti ati koriko to le wa lawọn ibi ti ọgbara maa ṣan gba kuro.
Ọgbẹni Clement sọ pe ọrọ yii ki i ṣe tijọba nikan o, o parọwọ sawọn ijọba ibilẹ, awọn ileeṣẹ nla, atawọn afẹnifẹre ẹda lati fọwọ sowọ pọ, ki wọn le ṣeto ati dena omiyale lati adugbo kan si omi-in, ọgbara ojo ko loun o ni i wo’le, onile ni o ni i gba fun un.