Jide Alabi
Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni Ọga Agba pata fun ẹṣọ oju popo nile wa, (Federal Road Safety Corps), Boboye Oyeyẹmi, paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ajọ naa pe ki wọn pada soju popo lati maa ba iṣe wọn lọ.
Atẹjade kan ti ọga to wa fun lila araalu lọyẹ, Bisi Kazeem, gbe jade lo sọ eleyii di mimọ. Aṣẹ yii waye lẹyin ti awọn ẹṣọ oju popo naa ti sa kuro loju ọna nitori iwọde SARS to waye ni ọsẹ diẹ sẹyin, ati bi awọn janduku ṣe kọ lu awọn ileesẹ wọn kan, ti wọn si dana sun un.
Ṣugbọn ni bayii, ọga wọn ti sọ pe ki gbogbo awọn ẹsọ oju popo yii pada si ẹnu iṣẹ, ko ṣai ki wọn nilọ pe ki wọn ri i pe awọn to n lo oju ọna pa ofin irinna mọ, ki wọn ri i pe wọn ko lufin to ni i ṣe pẹlu eto aabo, ki wọn si ri i pe ko si ijamba ni awọn oju ọna wa kaakiri