Iru ki waa leleyii, wọn pa Rotimi sinu oko l’Ọka Akoko, wọn tun ge ori rẹ lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Baba agbalagba kan, Rotimi Olukoju, lo ti pade iku ojiji lọna oko rẹ niluu Ọka Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko.

ALAROYE gbọ pe oku oloogbe ọhun to n ṣisẹ ọdẹ ni ileefowopamọ alabọọde kan to wa niluu Ọka, ni wọn ba nibi ti wọn pa a si loju ọna marosẹ to wa laarin Ọka si Iwarọ Ọka Akoko lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ***ọsẹ yii.

Ṣe lawọn onisẹẹbi ọhun ge ori ọkunrin naa lọ lẹyin ti wọn pa a tan, ti wọn si fi iyooku ara rẹ silẹ sibi tawọn eeyan ti ba a lọjọ keji.

Iṣẹlẹ yii atawọn iwa ọdaran mi-in to n waye lati nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni wọn lo ti da jinnijinni bo awọn eeyan agbegbe Akoko, eyi naa lo si ṣokunfa bi wọn ṣe n bẹ awọn ọlọpaa lati tete waa bẹrẹ iṣẹ wọn gẹgẹ bii ti ateẹyinwa.

Ọkan ninu awọn agbaaagba ilu Akoko, Alaaji Ibrahim Killani, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni iwa kokanmi tawọn ọlọpaa n hu lẹyin rogbodiyan to suyọ lori iwọde SARS ti wọn ṣe kọja ti mu ki iwa ọdaran tun gbilẹ si i kaakiri awọn ilu to to wa l’Akoko.

 

O ni Ọjọruu, Wẹsidee, yii kan naa, ni wọn ji awọn arinrinajo mẹta gbe pẹlu ìbọn niluu Ikakumọ Akoko to wa ni aala ipinlẹ Ondo ati Edo.

Ọlọkada kan to rin si asiko ti awọn ajinigbe naa n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ lo ni wọn fipa da duro, ti wọn si lu u ni aludaku ki wọn too fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ, ti wọn si ba tiwọn lọ.

O ni ileewosan ijọba to wa l’Akunnu Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, ni ọkunrin naa ti pada ji saye. Awọn mẹtẹẹta ti wọn ji gbe ọhun lo ni wọn ṣi wa ninu igbekun awọn to ji wọn gbe lasiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Adele Ọba Akunnu, Ọmọọba Tọlani Orogun, ni ohun to le fọkan awọn eeyan ilu balẹ patapata ni ki wọn gbe ibudo awọn ọmọ ogun wa si agbegbe naa, nitori pe ipinlẹ meji ọtọọtọ, Kogi ati Edo lawọn ba paala.

O ni awọn aginju nla nla to yi ilu awọn ka lawọn oniṣẹẹbi naa n lo gẹgẹ bii ibuba.

Pupọ awọn eeyan ti wọn n ṣiṣẹ agbẹ ni Ikakumọ, Akunnu ati Auga ni wọn ko laya lati lọọ ṣiṣẹ loko wọn mọ nitori ibẹru awọn ajinigbe gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ.

Nigba ta a kan si Ọgbẹni Razaq Rauf to jẹ ọga ọlọpaa patapata fun ẹkun Ikarẹ Akoko, ṣe lo rọ awọn ara agbegbe ọhun lati fọkan balẹ.

O ni awọn ọlọpaa ti n gbaradi lati peṣe aabo to peye fawọn eeyan ilu, ati pe ko ni i pẹ rara ti ọwọ yoo fi tẹ gbogbo awọn ọdaran to n fi agbegbe Akoko boju ṣiṣẹ ibi.

Leave a Reply