Faith Adebọla
Bijọba apapọ ṣe n laago ikilọ lasiko yii lori iwọde ayajọ EndSARS tawọn ọdọ kan n gbero lati ṣe logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, bẹẹ ni wọn tun n rawọ ẹbẹ sawọn ọdọ naa pe ki wọn ro ti ipo ẹlẹgẹ ti eto aabo wa lorileede wa lasiko yii, ki wọn jawọ ninu ṣiṣẹ iwọde ajọdun ọhun.
Igbimọ apapọ lori eto ọrọ-aje, National Economic Council (NEC) eyi ti Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ṣe alaga rẹ lo parọwa yii lasiko ipade igbimọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, l’Abuja.
Igbimọ to n gba ijọba apapọ nimọran ọhun sọ pe:
“Bo tilẹ jẹ pe a mọ ipa ti iwọde alaafia ti ko ninu eto ijọba dẹmokiresi lati fi ohun ti araalu fẹẹ jiroro le lori han, sibẹ, Igbimọ NEC n parọwa gidi sawọn ti wọn n gbero lati ṣewọde kaakiri ilu lati sami si ajọdun ayajọ EndSARS, pe ki wọn jawọ lori ẹ, ki wọn si wa ọna mi-in lati fikunlukun pẹlu ijọba.
Idi ni pe ipo ti eto aabo wa lorileede wa lọwọ yii gbẹgẹ gidi, o si ṣee ṣe ki iru iwọde bẹẹ di eyi tawọn janduku yoo ja gba mọ wọn lọwọ, awọn ti wọn si ti n wa nnkan ti wọn maa fi kẹwọ huwa ibi tẹlẹ le tun bẹrẹ si i dana ijangbọn lawọn ibi ti iwọde naa ba ti waye. ‘‘Igbimọ yii rọ yin ni, a gba yin lamọran ni, ẹ pa ero da lori iwọde ayajọ yii o.
Igbimọ naa tun ṣalaye pe awọn igbimọ oluṣewadii ati apẹtusaawọ tawọn ijọba ipinlẹ kọọkan gbe kalẹ lori awọn ẹsun ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ ẹni mọlẹ ti wọn fi kan awọn agbofinro ti ba iṣẹ wọn de ọna to jin, awọn kan lara igbimọ naa si ti jabọ fun ijọba apapọ, koda ijọba ti ya apo owo kan sọtọ lati fi pẹtu sọkan awọn ti wọn koju ifiyajẹni bẹẹ.
Wọn ni kawọn ọdọ fun ijọba laaye lati tubọ pari igbesẹ alaafia wọnyi, ki wọn ma ṣe tun dagba le ṣiṣe iwọde to tun le polukurumuṣu omi alaafia ati aabo kaakiri Naijiria.
Wọn ni kawọn to n fẹẹ ṣewọde naa tun wo awọn ọna mi-in ti wọn le gba fi ẹdun ọkan wọn han si ijọba lagbegbe wọn ati ijọba apapọ pẹlu.