Aderounmu Kazeem
Bi eto idibo ṣe n sunmọ etile, ọkan awọn eeyan kan ko balẹ mọ l’Ondo bayii, ohun to si n ka wọn laya ni bi gomina ipinlẹ naa ko ṣe ni fi ẹṣọ Amọtekun dunkooko mọ awọn ẹgbẹ alatako nibẹ.
Ọkan ninu awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti sọrọ, iyen ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, awọn gan-an ni wọn kọkọ pariwo sita pe Gomina Akeredolu ko gbọdọ lo ẹṣọ Amọtẹkun fi da nnkan ru fawọn o.
Ọkunrin kan ti wọn pe ni James Varnimbe, ẹni ti i ṣe akọwe gbogbo-gboo fun ẹgbẹ oṣelu naa lo sọrọ yii. O ni bo tilẹ je pe lakọ ni ẹgbẹ oṣelu oun wa bii ibọn fun imurasilẹ ibo gomina to maa waye l’Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, sibẹ o ṣe pataki ki awọn tete pariwo sita bayii pe Gomina Akeredolu ko gbọdọ gbiyanju lati lo awọn ẹṣọ Amọtẹkun fi halẹ mọ wa.
Ọkunrin yii fi kun un ọrọ ẹ pe ko ni i dara ti gomina naa ba n lo Amọtẹkun lati fi dunkoko mọ awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in.
O ni, ohun to dara ju fun kaluku bayii ni ki wọn huwa ọmọluabi, ki eto idibo ọhun le lọ wọọrọwọ, ki ajọ eleto idibo paapaa fi ootọ inu ṣiṣẹ wọn, ki idarudapọ ma si ṣe ru bii eefin rara ni ipinlẹ wọn.