Ẹ tete kede Ẹgbẹ Afẹnifẹre bii ẹgbẹ afẹmiṣofo-Ẹgbẹ awọn Hausa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Coalition of Nothern Groups (CNG) ti ni ki ijọba apapọ ilẹ Naijiria tete bẹrẹ si i ri ẹgbẹ agba Yoruba nni, Afẹnifẹre, gẹgẹ bii ẹgbẹ onijagidijagan ati adunkooko-mọ-ni.

Iwe kan lawọn ẹgbẹ yii fi sita to kede eyi niluu Abuja, iyẹn lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje ọdun 2021.

Agbẹnusọ ẹgbẹ CNG, Abdul-Azeez Suleiman, sọ pe awọn eeyan bii Baba Ayọ Adebanjọ to jẹ olori Afẹnifere atawọn mi-in bii wọn, ti wọn da ẹgbẹ to n dunkooko mọ ara yooku silẹ ko yẹ ki wọn maa yan fannda laarin ilu, o lo yẹ kijọba mu wọn gẹgẹ bii onijagidijagan ni ki wọn si da sẹria fun wọn.

CNG sọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ wọn, Abdul-Azeez Suleiman fi sita niluu Abuja lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii.

Ọkunrin Abdul-Azeez Suleiman yii sọ pe,  “Gbogbo ara la fi lodi sawọn eeyan ti wọn n gbe ibinu aye ọjọsi kiri. Ti wọn n tori ẹ lodi sawọn eeyan Naijiria to ku, ti wọn n lo awọn eeyan fun idaluru ati jagidijagan kaakiri.

“ A lodi sawọn to n ṣe iru eyi, nitori Awolọwọ to fẹẹ ṣejọba ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun un lawọn naa ṣe n daamu ara yooku, abuku ati titẹni loju mọlẹ la ka iwa wọn si”

Ohun ti awọn ẹgbẹ apapọ ilẹ Hausa yii ṣaa n wi lede kan ni pe ẹgbẹ to n da wahala silẹ ni Ẹgbẹ Afẹnifẹre to wa nilẹ Yoruba, wọn ni ohun to si yẹ kijọba apapọ Naijiria tete ṣe bayii ni ki wọn kede wọn bii onijagidijagan.

 

 

Leave a Reply