Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii iku ọmọ APC ti wọn lu loogun to fi ku l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iku ati ẹni to pa ọmọ ẹgbẹ APC to ku lasiko ija igboro to waye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọpin ọsẹ to kọja, lasiko eto abẹle ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti.

Ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Jide ni wọn pa ni Wọọdu kẹwaa, niluu Ado-Ekiti. A gbọ pe oogun ni wọn na ọmọkunrin naa, lẹyin eyi ni wọn gun un nigo, to si ku laipẹ ti wọn gbe e de ileewosa.

Ija ajaku akata la gbọ pe o waye laarin awọn ọdọ meji ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC. Abajade eto idibo to waye lọjọ yii la gbọ pe wọn n ja le lori to fi di pe wọn n nara wọn loogun, ti wọn si n gun ara wọn lọbẹ, eyi to pada yọri si iku ọmọkunrin ti wọn n pe ni Jide yii.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niluu Ado-Ekiti, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ẹni to pa ọmọkunrin yii.

O ni awọn ti n ba awọn adari APC nipinlẹ naa sọrọ lati le ṣawari ẹni to pa Jide. “A ti n sa gbogbo ipa wa lati fi pampẹ ofin mu ọdaran naa. A fẹẹ ri i daju pe a ṣe iwadii to daju lati le mọ awọn to da rogbodiyan naa silẹ.

“Loootọ, ọwọ ọlọpaa ko ti i tẹ ẹnikẹni lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn o da mi loju pe awọn agbofinro maa ṣa gbogbo ipa wọn lati le fi ododo iṣẹlẹ naa mulẹ, nitori Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, Ọgbẹni Tunde Mobayọ ko fi aye gba aibọwọ fun ofin.”

Leave a Reply