Ẹ waa wo tiṣa to n fipa ba awọn akẹkọọ ọkunrin to n kọ nileewe lo pọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ olukọ ileewe aladaani kan n’Ibadan, Ọlawuyi Ebenezer, ẹni to nifẹẹ si ko maa ba awọn akẹkọọ rẹ ọkunrin laṣepọ.

Nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii, CP Ngozi Onadeko, ṣafihan ọkunrin naa pẹlu awọn afurasi ọdaran mi-in tọwọ wọn tun tẹ fun iwa ọdaran lọlọkan-o-jọkan

Ebenezer, ẹni to pera ẹ lọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ, fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmọkunrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejila si mẹtala loun maa n ba laṣepọ

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo ba ọkunrin laṣepọ, ọmọọdun mẹtala ni mo ba sun.

“Ẹẹkan ni mo ba obinrin sun ri. Iyẹn waye nigba ti mo wa nileewe. Awọn ọmọkunrin ni mo n ba sun bayii. Ọkunrin meji ni mo ti ba laṣepọ. Akẹkọọ mi lawọn mejeeji.

“Iṣẹ olukọ ni mo n ṣe nileewe aladaani kan laduugbo Abẹbi, n’Ibadan.

“Idanwo ni mo ni ki ọkan ninu awọn akẹkọọ mi waa ba mi maaki nile ti mo fi ba a laṣepọ. Ki i ṣe pe mo fipa ba a ṣe e, mo sọ fun un ki n too ṣe e. O si gba fun mi nitori pe ko fẹ ki n feeli oun.”

Eyi kọ nigba akọkọ ti iranṣẹ eṣu yii yoo huwa to lodi sofin Ọlọrun yii. Gẹgẹ bọkunrin to pera ẹ lẹni ọgbọn ọdun yii ṣe fẹnu ara ẹ ṣalaye, “Mo ti ba ọmọkunrin kan naa laṣepọ ri nileewe ti mo ti kọkọ n ṣiṣẹ tẹlẹ ki n too de ibi ti mo wa yii.’’

Leave a Reply